A ko le maa ṣe aṣedanu mọ nipinlẹ Ogun, igba ọtun n bọ laipẹ - Aderinokun sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 15, 2022

A ko le maa ṣe aṣedanu mọ nipinlẹ Ogun, igba ọtun n bọ laipẹ - Aderinokun sọrọ


Oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe asiko ti to lati le gbogbo awọn ti ko kju oṣuwọn danu lọdun 2023.

O ni asiko naa ti to lati dẹkun aṣedanu nipinlẹ naa nipa lile awọn ti ko mọ nnkankan nipa oṣelu, paapaa idagbasoke ilu danu lọdun to n bọ.

Bakan naa lo sọ pe oun kan ṣoṣo to da oun loju ni pe itan maa yi pada lọdun to n bọ, nitori pe eto oṣelu to n bọ lọna yii, ẹgbẹ oṣelu APC maa pada lulẹ kọja sisọ ni.

O ni awọn olugbe aarin gbungbun ipinlẹ Ogun ni ẹtọ si awọn nnkan meremere, iyẹn nibi ipade to waye pẹlu awọn ara wọn, eyi ti wọn fi n gba awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun wọle nijọba ibilẹ Abẹokuta South, Ifọ ati Ewekoro.

Aderinokun ni oun wa fawọn eeyan oun, toun si gbọdọ ṣe ẹtọ to tọ fun lakoko to ba yẹ, nitori pe ko si aaye kankan fun ikuna.

"Mi o le ṣai ma ṣe ojuṣe mi fawọn eeyan mi, mo ni lati wa gbogbo ọna ti iya ko fi ni jẹ wọn nini eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ yii.

"Awọn opopona to wa niluu ati lẹyin odi Ifọ bajẹ kọja sisọ, emi gan-an mọ ọn lara. Ipenija kan naa yii la ni lagbegbe Ewekoro. Mo mọ pe nnkan maa yipada si rere lọdun 2023, nitori pe a ko le laju silẹ lati maa tẹle awọn to ti kuna lẹyin mọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI