Aye wa ni itumọ labẹ iṣakoso Gomina AbdulRazaq - Awọn olukọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 6, 2022

Aye wa ni itumọ labẹ iṣakoso Gomina AbdulRazaq - Awọn olukọ


Gbogbo awọn olukọ ile ẹkọ giga ti awọn olukọni, iyẹn Kwara State Colleges of Education ti sọ pe aye awọn dara, o si tun ni itumọ labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq to n ṣe ijọba lọwọ.
 
Opin ọsẹ to kọja yii l'awọn olukọ naa labẹ aburada Joint Academic Staff Union in Tertiary Institutions (JASUTI) gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori awọn ipa to n ko n'ipinlẹ naa, paapaa l'ẹka eto ẹkọ.
 
Nibẹ ni wọn tun ti dupẹ gidigidi lọwọ gomina naa fun bo ṣe bu ọwọ lu ọna ati awọn olukọ l'awọn ile ẹkọ kọlẹẹji ati gbogboniṣe ṣe n gba owo oṣu ati agbeyawo owo oṣu tuntun wọn, eyi ti wọn pe  ni Consolidated Polytechnics and Colleges of Education Academic Staff Salary Structure (CONPCASS).
 
Wọn lo ti pẹ ti et CONPCASS naa ti wa nilẹ, ti awọn iṣakoso to kọja ko bu ọwọ lu ṣaaju asiko ti gomina yii gbajọba.
 
Siwaju si i ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko kabamọ wi pe awọn dibo yan AbdulRazaq l'ọdun 2019, pẹlu ileri wi pe awọn yoo tun ṣagbatẹru ipadasipo rẹ lẹẹkeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI