Gómìnà Kwara gbé àgbéyẹ̀wò ètò ìṣúná ọdún 2022 lọ sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 13, 2022

Gómìnà Kwara gbé àgbéyẹ̀wò ètò ìṣúná ọdún 2022 lọ sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin


Lonii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara gbe agbeyẹwo eto iṣuna ọdun 2022 ti a wa yii pada sile igbimọ aṣofin lati bu ọwọ lu.

Owo to din diẹ ni igba biliọnu (N187.5b) naira ni Gomina AbdulRazaq gbe lọ ba awọn aṣofin ọhun lati fi ontẹ lu.

Abẹnugọn ile igbimọ naa, Ọnarebu Yakubu Salihu Danladi nigba to n ka ọrọ Gomina si gbogbo ile leti, lo ti jẹ ko di mimọ pe owo naa ti din diẹ si iye to wa tẹlẹ.

Gomina AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ naa sọ pe agbeyẹwo ọhun ni wọn yoo fi pari gbogbo awọn akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ, ti wọn yoo si tun san owo oṣu tuntun fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba kaakiri ẹka ileeṣẹ ijọba.

O ṣalaye pe biliọnu ₦189.6b naira ni wọn ti kọkọ bu ọwọ lu tẹlẹ, ko to di pe wọn tun agbeyẹwo rẹ ṣe, ti owo naa si ja wa silẹ si biliọnu ₦187.5b naira.

Ninu ọrọ olori ile igbimọ naa, Yakubu Salihu Danladi wa sọ pe ki igbimọ to n ri sọrọ bibu ọwọ lu eto iṣuna, iyẹn House Committee on Appropriation tubọ lọ ṣe agbeyẹwo naa daadaa, ko to di pe wọn bu ọwọ lu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI