Ikunlẹ abiyamọ o! Ile alaja mẹta tun da wo l'Ekoo, awọn eeyan lo farapa yannayanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 23, 2022

Ikunlẹ abiyamọ o! Ile alaja mẹta tun da wo l'Ekoo, awọn eeyan lo farapa yannayanna


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan ni a ko tii le f'idi iye awọn to farapa ati awọn to ku mulẹ ninu ijamba ile alaja mẹta kan to deede da wo lulẹ lagbegbe Muṣhin, nipinlẹ Eko mulẹ, sibẹ, ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn eeyan to wa nibẹ.

Adugbo kan ti wọn pe ni Ṣonuga, Palm Avenue, Mushin ni ijamba naa ti waye lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee, ti awọn eeyan si farapa kọja sisọ.
 
Gẹgẹ bi alakoso ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri n'ipinlẹ Eko, National Emergency Management Agency, NEMA, Ibrahim Farinloye ṣe ṣalaye, o sọ pe ni kete ti wọn ti fi ijamba naa to wọn leti, l'awọn oṣiṣẹ wọn ti dide lati lọ doola ẹmi awọon eeyan.
 
Farinloye sọ pe ọmọ kekere kan, ati agbalagba kan ni wọn ṣi ri gbe jade nibi ijamba naa, ati pe wọn ṣi n ṣiṣẹ lati wa awọn yooku to ṣee ṣe ki wọn ṣi wa ninu ile.
 
Nigba toun naa n sọrọ, akọwe agba lẹka ajọ NEMA n'ipinlẹ Eko, Dọkita Olufẹmi Ọkẹ-Ọsanyintolu, sọ pe awọn ti gbọ pe awọn obinrin meji kan ṣi wa ninu ile lakoko ijamba naa, ati pe wọn ko tii ri wọn yọ jade.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI