Wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ti wọn pe ti olohun gan-an lo de ba awọn afurasi adigunjale mẹta kan t'ọwọ palaba wọn segi laipẹ yii n'ipinlẹ Ogun.
Ọwọ awọn ẹṣọ aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps lo tẹ wọn, ti a si gbọ pe o ti pẹ ti wọn ti wa lẹnu iṣẹ buruku ọhun.
Awọn mẹtẹẹta naa ni wọn pe orukọ wọn ni Ọpẹoluwa
Alade Sunday, ọmọ ọdun mẹtalelogun; Stanley, ati Hammẹd Isiaka, ti wọn tun n pe ni Jack Ọmọ
Baala.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn oṣiṣẹ So-Safe Corps, ti ẹkun Adiyan-Alausa Onibudo, ijọba ibilẹ Ifọ lo tẹ wọn.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja la gbọ pe awọn eeyan yii lọ jale lagbegbe Mercy, Onibudo, ti wọn si ji ọpọlọpọ dukia ko nibẹ, iroyin naa lo si tẹ ẹṣọ yii lọwọ l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.
Ninu iwadii la gbọ pe ọwọ ti tẹ Ọpẹoluwa Alade Sunday, ẹni to pada jẹwọ pe lootọ loun wa lara awọ to lọ jale, nibẹ lo ti mu wọn lọ sibi t'awọn yooku ẹ wa ni otẹẹli Anthony Garden, to wa ni Doland Bus Stop, nitosi ibudokọ Agege.
Ibẹ lọwọ palaba Stanley ati Hammẹd ti segi, ti awọn naa si jẹwọ pe lotitọ ni.
Agbẹnusọ f'awọn So-Safe n'ipinlẹ Ogun, Mọruf Yusuf to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe nibi ti wọno ti fẹẹ mu wọn, l'awọn kan na papa bora lara wọn.
Mọruf sọ pe ninu iwadii l'awọn tọwọ tẹ yii ti sọ pe ọwọ awọn to na papa bora l'awọn ibọn ti wọn n lo lati fi jale wa.
No comments:
Post a Comment