Nitori iwa jibiti, ijọba Ọṣun da olukọ kan duro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 27, 2022

Nitori iwa jibiti, ijọba Ọṣun da olukọ kan duro


Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede sita wi pe awọn ti yọ olukọ kan, Abimbọla Oloowokere danu kuro lẹnu iṣẹ olukọ, lori bo ṣe n lu awọn olukọ ẹgbẹ rẹ ni jibiti.

Owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni wọn sọ pe Olowookere lu awọn olukọ ti wọn ṣẹṣẹ gba sẹnu iṣẹ ijọba.

AWIKONKO gbọ pe ko si nnkan meji ti Oloowokere fi n lu awọn olukọ naa ni jibiti, bi ko ṣe ẹtanjẹ wi pe oun yoo ba wọn ṣe e ti wọn yoo fi lọ maa kẹkọọ nibi to ba wu wọn.

Ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, nigba to n kede, sọ pe awọn olukọ ti wọn ṣẹṣẹ gba si iṣẹ ni ẹkun Ọṣun East la gbọ pe Olowookere gba owo lọwọ wọn.

Olobo naa lo ta ileeṣẹ eto ẹkọ lolobo, ti wọn fi bẹrẹ iwadii, ko to di pe aṣiri naa tu si wọn lọwọ.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ, Ọnarebu Fọlọrunṣhọ Ọladoyin nigba to n sọrọ bu ẹnu atẹ lu iwa ti Olowookere hu, to si gba awọn olukọ tuntun naa lamọran lati ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni lu wọn ni jibiti pẹlu ẹtanjẹ.

Ọladoyin jẹ ko di mimọ pe ijọba ipinlẹ naa ti gba ẹgbẹrun kan olukọ fun ipele akọkọ igbanisiṣẹ, to si ni ileeṣẹ naa ni yoo sọ ibi ti awọn olukọ naa yoo ti ṣiṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI