Pasitọ to n ta omi ayẹta wọ gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 20, 2022

Pasitọ to n ta omi ayẹta wọ gau


Wọn ti gba awọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri orileede yii lati ṣe iwadii alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi New Jerusalem Deliverance Ministry, Pasitọ Peter Michonza, lori omi ayẹta to sọ pe oun n ta f'awọn araalu kaakiri.
 
Alaga ijọba ibilẹ Okene, Onimọ-ẹrọ Abdulrazaq Muhammad lo rawọ ẹbẹ naa laipẹ yii, lẹyin ti fọnran pasitọ naa gba ori ikanni ayelujara, nibi to ti n ta omi ayẹta f'awọn eeyan.
 
Onimọ-ẹrọ Muhammad tun rọ ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹẹni, CAN, ẹgbẹ oniṣegun oyinbo lorileede Naijiria, NMA at'awọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri lati tọpinpin ọkunrin naa daadaa, ko to pẹ ju.
 
Bakan naa lo sọ pe loootọ ni iwadii ti bẹrẹ lori Peter, lori ohun to n ṣe, eyi to sọ pe ko ba ilana ati ofin ẹsin Kristẹẹni mu.
 
Pasitọ Peter Michonza siwaju sii la gbọ pe o tun da ile igbẹbi silẹ, nibi to ti  n gbẹbi f'awọn alaboyun ti asiko ibimọ ba to fun wọn, eyi to ni ko ba ilana ati ofin awọn oniṣegun oyinbo mu, to si lo ti fa iku ọpọ awọn eeyan lawujọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI