Adron Homes ṣagbekalẹ eto 'Lemon Friday Plus Promo' fawọn onibara pẹlu anfaani ida aadọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 23, 2025

Adron Homes ṣagbekalẹ eto 'Lemon Friday Plus Promo' fawọn onibara pẹlu anfaani ida aadọta


Gẹgẹ bi ọdun 2025 ṣe ti n kasẹ nilẹ diẹdiẹ, awọn alakoso ileeṣẹ to gbajugbaja nidi okoowo ilẹ ati dukia kaakiri agbaye, Adron Homes and Properties Limited tun ti ṣagbekalẹ anfaani nla ti yoo sọ ọpọ di lanlọọdu.

Anfaani naa ni wọn gbe kalẹ fun gbogbo awọn onibara wọn tẹlẹ ati tuntun, lati le jẹ ki wọn maa san owo dukia to ba wu wọn diẹdiẹ, pẹlu ida aadọta ti wọn ti yọ kuro.

Eto naa ni wọn pe ni Lemon Friday Plus Promo, eyi ti wọn fi ṣagbeleke fun ipolongo Lemon Friday to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita l'Ọjọbọ, wọn ni igbesẹ yii ni lati jẹ ki ọpọ eeyan di onidukia nipa sisan owow diẹdiẹ pẹlu bi wọn ṣe da gbogbo dukia wọn si ida aadọta.

Alakoso agba, Arabinrin Adenike Ajobo ninu atẹjade ọhun ṣalaye pe igbesẹ ọhun ṣẹyin bi ileeṣẹ Adron Homes ṣe n farajin lati ro ọpọ ọmọ Naijiria lagbara, ki wọn le di onile lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI