Ajọ eleto idibo fi orukọ awọn oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun sita, wọn yọ oludije PDP danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 4, 2022

Ajọ eleto idibo fi orukọ awọn oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun sita, wọn yọ oludije PDP danu


Ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, Independent National Electoral Commission, INEC ti fi orukọ awọn oludije s'ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu kọọkan sita, lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
 
Gbogbo orukọ awọn oludije ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu to lẹtọọ lati jade du ipo lo jade, yatọ si oludije s'ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
 
Ko si nnkan meji to fa a, to mu ki orukọ oludije kankan ma jade, bi ko ṣe ti ẹjọ to n lọ lọwọ nile ẹjọ.
 
Ọtunba Jimi Lawal, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ati Ọnarebu Ladi Adebutu l'awọn mẹtẹẹta ti wọn jọ gbe ara wọn lọ sile ẹjọ lori ipo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI