Ajoji ni Atiku ati Obi jẹ nilẹ Yoruba, ẹ ma ṣe dibo fun wọn - Tinubu kilọ f'awọn ara Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 16, 2022

Ajoji ni Atiku ati Obi jẹ nilẹ Yoruba, ẹ ma ṣe dibo fun wọn - Tinubu kilọ f'awọn ara Ekiti


Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti kilọ fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ekiti lati ma ṣe dibo f'awọn ajoji ti wọn n bọ lati polongo ibo fun wọn.
  
Aṣiwaju Tinubu sọ pe ki awọn araalu ma ṣe gba awọn alatako rẹ ninu eto idibo s'ipo aarẹ to n bọ lọna, Alaaji Atiku Abubakar lati inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ati Peter Obi toun jade lati inu ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) laaye lakoko eto idibo, nitori pe ajoji ni wọn jẹ.
 
Tinubu lo sọrọ yii nibi ayẹyẹ ibura fun Gomina Biọdun Oyebanji ti ipinlẹ Ekiti lonii, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2022.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ki awọn araalu kẹyin si wọn, ki wọn si diju fun wọn nigbakugba ti wọn ba ti wa lati polongo ibo fun, ki wọn si ṣebi ẹni pe wọn ko mọ wọn ri rara.
 
“Idibo miran lo n bọ ninu oṣu keji, ọdun 2022. Wọn n bọ o. Ọkan maa pe ara rẹ ni Atiku, ẹnikeji maa pe ara rẹ ni Peter Obi. Ẹ ko mọ wọn ri o. Ẹnikan ṣoṣo ti ẹ mọ ni Bọla Ahmẹd Tinubu, ẹ si gbọdọ dibo ti ko din ni ida marundinlọgọrun-un fun  mi.”
 
Bakan naa lo sọ pe gbogbo ileri toun ba ṣe patapata loun yoo ri daju pe wọn wa si imuṣẹ, nitori pe oun yoo tọju awọn araalu ati awọn ọmọ wọn lapapọ.
 
“Ẹ ma ṣe lọ jinna, awọn to maa ṣe ileri fun un yin, ti wọn si maa mu awọn ileri naa ṣe ni wọn wa nibi. A maa tọju ẹyin ati awọn ọmọ yin. A maa fun un yin ni ọjọ iwaju rere. A n ṣeleri Naijiria ti yoo dara fun un yin. Ki Ọlọrun Ọba tubọ maa bukun fun wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI