Aye o! Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi jona di eeru - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 10, 2022

Aye o! Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi jona di eeru


Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan ni ko tii s'ẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa bi ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kogi to wa niluu Lọkọja ṣe jọna, to si jona kọja sisọ.


Nnkan bi aago mẹjọ aarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde la gbọ pe ina deedee ṣẹyọ ninu gbọngan ile igbimọ aṣofin naa, to si jẹ pe ki oloju too ṣẹ ẹ, ẹpa ko boro mọ.

Nigba to n sọrọ, abẹnugọn ile igbimọ aṣofin naa, Ọmọọba Mathew Kọlawọle sọ pe oun ko le sọ pato nkan to ṣokunfa bi ile igbimọ naa ṣe jona, ṣugbọn oun yoo gba awọn eleto aabo laaye lati ṣiṣẹ iwadii.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe bi ile igbimọ naa ṣe jona, ko da wọn duro lati jokoo lori ọrọ ileeṣẹ simẹnti Dangote ti wọn ti pa laipẹ yii, ki wọn si wa ọna abayọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI