Ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi: Ọga agba pata fun Fijilante b'awọn Musulumi yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 10, 2022

Ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi: Ọga agba pata fun Fijilante b'awọn Musulumi yọ



Ọga agba patapata fun ẹgbẹ fijilante lorileede Naijiria, Vigilante Group of Nigeria, Ajagunfẹyinti Abubakar Umar Bakori ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin Musulumi kaakiri agbaye, paapaa lorileede yii yọ ayajọ ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi Muhammed.

Ninu atẹjade ti Ọmọwe Umar Bakori fi sita lati ọwọ igbakeji agbẹnusọ wọn, Ọmọwe Samuel Olukunle Adeyọyin lonii, ọjọ Aje, Mọnde lo ti sọ pe ayẹyẹ t'awọn eeyan ko gbọdọ gbagbe ni.
 
Ọga agba naa sọ pe inu oun dun pe Allah da ẹmi oun at'awọn eeyan si titi di asiko yii, to si gbadura pe ki ajalu ma ṣe kan ẹnikẹni lorileede yii mọ.
 
"Ki ibukun Allah tan imọlẹ si ọna to lọ si ibi idunnu, ifọkanbalẹ ati aṣeyọri fun iwọ ati idile rẹ. A ku ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi 'Eid-El-Maulud'. Eyi ni ikini ati adura ayẹyẹ ọjọ ibi Anọbi lati ọwọ apaṣẹ agba apata fun ẹgbẹ Fijilante, Ọmọwe Abubakar Umar Bakori si gbogbo Musulumi l'ọkunrin ati l'obinrin.

"Ọga agba fi idunnu rẹ han si Allah to da ẹmi wa ati gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ wa si lati tun ri ayayọ ọjọ ibi Anọbi Muhammed. Alakoso agba sọ pe orileede Naijiria la asiko ayẹwo kọja bayii, lakoko ti eto aabo mẹhẹ ni gbogbo agbegbe orileede yii.
 
"Alakoso agba wa gboriyin fun akitiyan gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata lori bi wọn ṣe n gbiyanju lati daabo bo ẹmi ati dukia araalu, eyi ti wọn ti n ṣe sẹyin to pọ, ati awọn eyi ti wọn n ṣe lọwọ.
 
"Awọn oṣiṣẹ wa ti gbogun ti awọn agbebọn, awọn ajinigbe, ati awọn oniṣẹ ibi miran kaakiri.

"Ọga agba wa gba awọn oṣiṣẹ patapata lamọran lati tubọ kun fun adura, pẹlu bi wọn ṣe n duro de Aarẹ lati bu ọwọ lu iwe abadofin ti yoo fi ẹsẹ wọn mulẹ lati ṣiṣẹ aabo lorileede yii. Bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun mu gbogbo awọn erongba wọn wa si imuṣẹ ni ọla yẹyẹ yii.

"Bẹẹ ni ọga agba tun sọ f'awọn oṣiṣẹ lati maa wa ni ifura ati ikiyesara, ki wọn si duro giri lori eto aabo, ati pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku, lati rii daju pe ẹmi ati dukia araalu ko si ninu ewu."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI