Ẹ gbọ ohun ti Gomina AbdulRazaq sọ nipa Olupako tilu Share lọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 28, 2022

Ẹ gbọ ohun ti Gomina AbdulRazaq sọ nipa Olupako tilu Share lọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ


Ọjọbọ, Tọsidee ana ni ayẹyẹ ọjọ ibi Olupako tiluu Sharẹ n'ipinlẹ Kwara, Ọba Ọlawale Haruna Ilufẹmiloye, ti gbogbo awọn ololufẹ rẹ si kii ku oriire anfaani ti ọdun yii.
 
Lara awọn ti ko gbẹyin lati ba Kabiyesi naa yọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ naa, ẹni to ṣapejuwe ọba ọhun gẹgẹ bi ẹni to n gbe alaafia ati iṣọkan larugẹ laaarin ilu, paapaa agbegbe rẹ.

Ninu atẹjade ti Gomina fi sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye lo ti sọ pe iwuri ni iṣakoso ọba maa n jẹ f'oun ni gbogbo ipa pẹlu bo ṣe n dari ilu to jẹ ọba le lori ati agbegbe ẹ.
 
O ni lara awọn ọba alaye to wa n'ipo akọkọ ti wọn fi n gbadura fun ọba ni Ọba Olupako jẹ, nitori pe ifẹ to ni si awọn ara ilu ẹ ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
 
O wa gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun kabiyesi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI