Ẹgbẹ akọroyin ni Kwara rawọ ẹbe s'ijọba lori awọn akọroyin ti wọn wa lahamọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 16, 2022

Ẹgbẹ akọroyin ni Kwara rawọ ẹbe s'ijọba lori awọn akọroyin ti wọn wa lahamọ


Ẹgbẹ awọn akọroyin n'ipinlẹ Kwara ti rawọ ẹbẹ s'ijọba ipinlẹ naa lati fi oju aanu wo awọn akọroyin meji ti wọn wa lahamọ lori ẹsun ibanilorukọ ti wọn fi kan wọn laipẹ yii.

Ninu atẹjade ti alaga ati akọwe ẹgbẹ awọn akọroyin, nipinlẹ naa, 'Lanre Ahmẹd ati Ọmọtayọ Ayanda fi sita laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ọrọ to ṣee yanju labẹle ni ọrọ yii.

Wọn lotitọ, awọn akọroyin mejeeji naa ti ṣe kọja ohun to yẹ, ṣugbọn sibẹ, ijọba ni lati wo wọn gẹgẹ bii pe wọn ko mọ nnkan ti wọn n ṣe lasiko naa ni.

"Ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Kwara n rawọ ẹbẹ si akọwe gomina, Rafiu Ajakaye lati yọwọ kuro lori ẹsun to fi kan awọn ọmọ ẹgbẹ wọon meji, Dare ati Abdulrasheed Akọgun, ti wọn ti mọ ọgba ẹwọn Mandala to wa niluu Ilọrin, lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti wọn fi kan oun ati ọga ẹ lori ikanni wasaapu to gbajumọ daadaa.

"Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa lo bi iwe ẹsun si ọdọ ọlọpaa, eyi to mu ki wọn f'oju wọn ba ile-ẹjọ jẹ eyi to banilọkanjẹ, o si burujai, ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ naa ko si tii sinmi lori awuyewuye ti ọrọ naa ti da silẹ niluu, ti a si nigbagbọ pe a maa yanju ẹ ni tubi-inubi, ti gbogbo rẹ yoo si lọ silẹ patapata.

"Ju gbogbo rẹ lọ, ninu ẹmi wi pe ohun to ba ṣẹlẹ si ẹnikan, o ti ṣẹlẹ si gbogbo eeyan lo jẹ ki awa alakoso ẹgbẹ akọroyin dide si ọrọ naa lati bi ọjọ meloo kan sẹyin, lati rii daju pe a yanju awọn iṣelẹ naa to n ṣẹlẹ si Dare Akọgun aati ẹgbọn rẹ, Abdulrasheed Akọgun, bo tilẹ jẹ pe a ko fẹ ki ọrọ naa jade sita.

"Akọwe ẹgbẹ wa lapapọ ti gbọ si ọrọ yii, toun naa si ti da si. Ẹgbẹ wa, wa n fi anfaani yii lati dupẹ lọwọ ijọba lori bi wọn ṣe n ṣe iranlọwọ f'awọn akọroyin, pẹlu ileri wi pe ajọṣepọ to dan mọnran yoo tubọ wa laaarin wọn."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI