Ẹ wo aragbayamuyamu ọja igbalode agbaye ti ijọba Kwara ṣẹṣẹ pari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 16, 2022

Ẹ wo aragbayamuyamu ọja igbalode agbaye ti ijọba Kwara ṣẹṣẹ pari


Ko sẹni to de ọja igbalode agbaye ti ijọba ipinlẹ Kwara ṣẹṣẹ kọ pari niluu Gbugbu, ijọba ibilẹ Edu, ti ko nii ki aje ku ikalẹ, koda ti ko nii mọ pe idagbasoke nla ti de ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa.

Ọja naa ti wọn pe ni ọja Gbugbu lo kun fun ṣọọbu ti wọn n tipa mejilelogun, ati isọ igba {200 shops}, pẹlu ṣalanga kaakiri fun irọrun awọn ọlọja, koda, ti ibudo awọn eleto aabo naa ko tun gbẹyin.

Yatọ awọn nnkan wọnyi, a gbọ pe omi igbalode naa tun wa nibẹ fun lilo awọn eeyan, eyi ti yoo mu ayedẹrun f'awọn araalu ti wọn n wa sibẹ lojoojumọ.
 
Nigba to n sọrọ, Gomina AbdulRazaq sọ pe inu oun dun fun ipele ti kikọ ọja naa de duro, to si ni ipele meji yooku ni wọn yoo ti fi ibusọ ẹran, teṣan ọlọpaa, ileeṣẹ panapana, ibi igbe-ọkọ-si, ọfiisi at'awọn nnkan miran kun-un.
 










No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI