Ijọba kede MacGregor gẹgẹ bi Olu Orile Ilawọ tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 21, 2022

Ijọba kede MacGregor gẹgẹ bi Olu Orile Ilawọ tuntun


Ijọba ibilẹ Ọdẹda ti kede Oloye Oluṣẹgun Alexander Macgregor gẹgẹ bi ọmọ oye fun ipo ọba ilu Ilawọ Orile to wa n’ijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun.

Ọjọbọ tii ṣe Tọside ana ni ileeṣẹ ijọba ibilẹ Ọdẹda labẹ iṣakoso Ọnarebu Arabinrin Fọlaṣade Adeyẹmọ kede Oloye MacGregor sita ninu atẹjade ti akọwe ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Makinde Zacheus Adio bu ọwọ lu.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ibo mẹfa ni Oloye MacGregor ni ninu ibo mẹsan ti awọn Oloye ti wọn yan dipo awọn afọbajẹ (Warrant Chief) di lọjọ naa, eyi to jẹ ko jawe ninu awọn marun-un ti wọn gba fọọmu fun ipo ọba.

Awọn marun-un to gba fọọmu lati du ipo Olu Orile Ilawọ naa ni: Ṣowunmi Joseph, Fatai Ṣodimu, Oluṣẹgun MacGregor, Lawrence Ogunsanya ati Adio Ọmọgoriọla Ṣodipọ.

Ninu atẹjade naa, a gbọ pe ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ (Ministry of Chieftaincy and Local Government Affairs) n’ipinlẹ Ogun lo fun wọn laṣẹ lati lọ ṣagbatẹru eto idibo niluu Ilawọ.

O ni iwe aṣẹ t’awọn gba lọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii ti nọmba rẹ jẹ CHM II/4/145, ati eyi ti wọn gba lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun yii ti nọmba rẹ jẹ CHM II/4/154 lo fun wọn laṣẹ lati bẹrẹ eto idibo.

Bakan naa lo sọ pe bi wọn ṣe dibo yan MacGregor l’Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kẹtala, ọsu kẹwaa, ọdun 2022 niluu Kẹgunmẹla gẹgẹ ni ibamu pẹlu iwe ofin oye jijẹ.

O jẹ ko ye wa pe Oloye Olufade Anthony Ajani lo ṣakoso eto idibo naa, to si ni lara awọn to wa nibẹ ni Ọgbẹni Kashimawo Arẹmu Bakare to jẹ akọwe idagbasoke agbegbe Abẹlu Ilawọ, Arabinrin Khadijat Badejọ at’awọn oloye miran niluu Ilawọ.

Siwaju sii, ẹnikan to sunmọ ijọba ibilẹ Ọdẹda daadaa to tun f’idi eto idibo naa mulẹ ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori awọn igbesẹ ti wọn gbe lati fi yan ọba.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ko si ẹnikan to le da ṣe ayidayida orukọ awọn afọbajẹ. Lati jẹ ọba, o ni eto labẹ ofin, gbogbo eto to si yẹ la tẹle patapata n’ijọba ibilẹ Ọdẹda nitori pe a jẹ ẹni to n tẹle ofin.

“Mo fẹ jẹ ki ẹ mọ pe kii ṣe ijọba ibilẹ nikan lo da ṣe eto idibo yii, a tun ni awọn ọga loke ti a maa gba aṣẹ lọwọ wọn, awọn ni ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ {Ministry of Local Government and Chieftaincy Affairs}, ti a ko ba tẹle ofin ati gbogbo nnkan to yẹ ka tẹle, a ko le ṣe e, awọn ni wọn fun wa l’aṣẹ pe ka bẹrẹ eto naa.

“Laarin ẹ ni awọn oloye kọ awọn orukọ kan ranṣẹ si wa, pẹlu orukọ awọn ọmọ oye. Gbogbo nnkan ti wọn kọ wa la ṣe agbeyẹwo ẹ finnifinni. Labẹ ofin oye jijẹ ti a mọ si ‘Chief Law’, ko tii si gasẹẹti ti wọn fi n yan ọba niluu Orile Ilawọ, lati f’idi rẹ mulẹ pe awọn idile ti yoo maa jẹ ọba ree.

“Bakan naa ni ko tun si gasẹẹti wi pe awọn eleyi ni afọbajẹ. Igbesẹ ti a si rii pe o yẹ ka gbe la gbe. Gbogbo ẹ o si ni akọsilẹ. Akọwe ijọba ibilẹ lo lọ ṣagbatẹru ẹ, ṣugbọn nitori pe awọn agbaagba lo n bọ, lo jẹ ki emi naa wa lori ijoko lọjọ yẹn. Akọwe lo ṣoju fun ijọba nibẹ. Ọjọ naa la pe gbogbo awọn baba patapata to fi mọ baba Oluwo.

“Gbogbo wọn ni wọn wa si ọfiisi wa, a ni fọnran ati fọto gbogbo ẹ lọwọ. Awọn baba Oluwo kọ orukọ awọn to gbọdọ wa nibẹ. Bakan naa l’awọn oloye miran naa tun kọ orukọ ti wọn. B’awọn kan ṣe n sọ pe orukọ t’awọn kan kọ ko tẹ wọn lọrun, bẹẹ l’awọn miran sọ pe orukọ t’awọn tiṣaaju kọ naa ko tẹ wọn lọrun. Eyi lo jẹ ka jokoo, ti a si ṣe agbeyẹwo orukọ mejeeji. A si rii pe orukọ mẹta pataki ṣe koko nibẹ.

“A beere orukọ awọn to wa nibẹ nigba ti wọn jẹ ọba akọkọ, wọn darukọ Oluwo, Osi oloye miran ti mi o ranti bayii. Orukọ awọn mẹta yii la kọkọ fi sinu ẹ. Lẹyin ẹ la gba aafin Ọṣilẹ ti Oke-Ọna to jẹ olori wọn lọ, koda, a tun lọ s’ọdọ Alakẹ ilẹ Ẹgba lati ba wa ṣagbeyẹwo awọn orukọ yẹn. Awọn Kabiyesi yii lo fun wa lorukọ awọn oloye Ilawọ ti wọn ṣee f’ọkan tan, to si ni iwe ẹri ti a gba. A ko fẹẹ ṣe ojusaaju lo jẹ ka gbe igbesẹ naa.

“Awọn oloye to wa ninu orukọ yii, eyi to kere ju ninu wọn lọjọ ori, lo jẹ aadọrin ọdun, agbalagba ni gbogbo wọn. A tun gbe awọn orukọ naa lọ sileeṣẹ ijọba ibilẹ ati idagbasoke lati f’ọwọ si i. Orukọ eeyan mẹwaa la kọ lọ sibẹ, orukọ eeyan mẹsan ni wọn bu ọwọ lu fun wa. Lẹyin ẹ la kọ iwe si gbogbo awọn oloye ti orukọ wọn wa ninu iwe naa.

“To ba ti di ọrọ afọbajẹ pajawiri ti a mọ si ‘Warrant Chiefs’, ọrọ naa ti kuro lọdọ igbimọ awọn oloye, o ti di pe gbogbo ẹni to ba wa ninu orukọ awọn afọbajẹ pajawiri, ẹnikan, ibo kan ni. Ko di dandan ki gbogbo oloye ilu wa nibi eto idibo.

“Awọn oloye yii ni wọn lọ jokoo laaarin ara wọn lati f’ẹnuko lori ọjọ idibo. Ọjọ mẹrinla la fun wọn lati ṣe gbogbo eto to yẹ ki wọn ṣe. Lẹyin ẹ ni wọn pe wa. Akọwe wọn lo kọ lẹta si wa wi pe awọn ti ṣetan, ti wọn si jẹ ka mọ ọjọ ti wọn mu ninu lẹta ti wọn fi ranṣẹ si wa. Gbogbo wọn la pelati ranṣẹ si awọn to fẹẹ jẹ ọba.

“Igba ti a de ori ijokoo ni wọn bẹrẹ sii yan ẹni ti wọn fẹ. Awa ko mọ awọn to wa nibẹ ri, awọn ni wọn ṣe gbogbo eto naa, awa kan wa nibẹ lati ṣe abojuto ni. Wọn ko tii ni eto ti wọn fi n jẹ ọba lati mọ idile ti ipo ọba kan lo jẹ ka gbe igbimọ afọbajẹ pajawiri dide. Akọwe ijọba ibilẹ lo ṣe adari eto lọjọ yẹn, ti akọsilẹ si wa, koda, fọnran ati fọto nnkan ti a ṣe wa pẹlu.

“Awọn ọmọ Ilawọ ti wọn wa nibẹ lọjọ naa le ni ọọdunrun {300}. A ti gbe esi abajade wa lọ si ọdọ awọn ọga wa lati wo o, bẹẹ la tun ti fi ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri sọrọ eto idajọ. Ẹni to ba ni ohunkohun lọkan le lọ s’ọdọ awọn ọga wa lati ṣe iwadii. Ọrẹ araalu ni wa n’ijọba ibilẹ Ọdẹda, a si duro lori idajọ ododo {justice, fairness and equity}. Gbogbo eyi ti wọn n sọ kaakiri kii ṣe ti wa, alaafia la duro fun.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI