Ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe opopona abẹ-ilẹ ti Geri-Alimi to dẹnukọlẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 16, 2022

Ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe opopona abẹ-ilẹ ti Geri-Alimi to dẹnukọlẹ


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti paṣẹ wi pe k'awọn agbaṣẹṣe fun iṣẹ opopona bẹrẹ atunṣe opopona abẹ-ilẹ ti Geri Alimi, iyẹn Geri Alimi Diamond Underpass to wa niluu Ilọrin, eyi to d'ẹnukọlẹ fun gbigba.
 
Ohun ti a gbọ ni pe, gomina ana, Abdulfatai Ahmẹd lo ṣe opopona naa pẹlu biliọnu mẹrin din diẹ N3.7b naira, lakoko to wa ni iṣakoso, ṣugbọn ti wọn ni o jẹ kayeefi wi pe opopona naa tete dẹnukọlẹ.

Asiko ti wọn ni iṣakoso Ahmẹd fẹẹ kogba wọle l'ọdun 2019 ni wọn pari opopona yii, ti wọn si ṣi i fun lilo araalu.

Opopona ọhun la gbọ pe o dẹnukọlẹ patapata f'awọn araalu lati gbe mọto wọn gba, eyi to mu ki wọn maa pẹ ọna gba.
 
Ni bayii, a gbọ pe ijọba ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki atunṣe bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, fun irọrun araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI