Ọlọrun lo maa sọ Aarẹ Naijiria laaarin Peter Obi ati Atiku Abubakar - Wolii Ayọdele sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 6, 2022

Ọlọrun lo maa sọ Aarẹ Naijiria laaarin Peter Obi ati Atiku Abubakar - Wolii Ayọdele sọrọ


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayọdele, ti sọ pe ọkan ninu oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ati oludije s'ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ni yoo di aarẹ Naijiria.

Wolii Ayọdele sọ pe oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, presidential candidate, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, ko si lara awọn ti yoo jijakadi lati du ipo naa l'ọdun 2023.
 
Gbajugbaja iranṣẹ Ọlọrun naa, to tun fẹran lati maa sọ asọtẹlẹ lo sọrọ yii lakoko to n b'akoroyin kan sọrọ n'ipinlẹ Eko.
 
Wolii Ayọdele jẹ ko di mimọ pe Ọlọrun nikan lo le sọ ẹni yoo di aarẹ Naijiria lọdun 2023, to si ni gbogbo awọn to n pariwo lasiko yii kan n pariwo lasan ni, wọn kii ṣe Ọlọrun.
 
O tẹsiwaju pe Ọlọrun ko nii wo ti ẹya, tabi ipo, tabi agbegbe ko to di pe o yan ẹni ti yoo di aarẹ Naijiria lọdun to n bọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “2023 wa laaarin Peter Obi ati Atiku; awọn mejeeji yii nikan ni wọn n jijakadi fun un. Mi o ri Tinubu wi pe o n lọ sibikibi. Awọn meji ti wọn n fi tọkantọkan jijakadi fun idibo 2023 naa niyẹn.
 
“Awọn ọmọ orileede Naijiria gbọdọ sọra wọn gidi, wọn si gbọdọ kiyesara lori idibo ọdun 2023, nitori pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ; idibo naa le da wahala ati rudurudu silẹ, o si gbẹgẹ ju awọn eyi to ti n waye tẹlẹ lọ.
 
“Ọlọrun ko nii wo ti ẹya tabi agbegbe, ko fẹ tikẹẹti Musulumii ati Musulumi. Ọlọrun maa mu oludije laaarin awọn to n jijakadi. Ijakadi naa si wa laaarin Obi ati Atiku.
 
“Naijiria ṣi maa dara ṣugbọn kii ṣe gbogbo rẹ. Naijiria ti bajẹ, ati pe wọn kan maa gbiyanju lati gbe e si ipo to yẹ ko wa. Iṣakoso to n bọ maa dara ju eyi to n kọja lọ.
 
“Awọn eeyan maa jade lọpọ yanturu lati dibo, BVAS yoo si jẹ iṣoro nla, ati pe ajọ INEC gbọdọ ṣiṣẹ takuntakun lori eyi, INEC ko fẹẹ yi ibo yii rara. Idibo ti yoo ṣojuṣaara gidi ni eyi to n bọ yii yoo jẹ, ṣugbọn o ṣee ṣe ki ija fẹẹ waye, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, idibo yii ko nii dabi awọn eyi to ti n waye tẹlẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI