Oriire nla: Ipatẹ ọja agbaye fẹẹ waye ni Kwara lara-ọtọ l'oṣu kejila, ọdun yii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 13, 2022

Oriire nla: Ipatẹ ọja agbaye fẹẹ waye ni Kwara lara-ọtọ l'oṣu kejila, ọdun yii


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ipinlẹ Kwara lati ṣagbekalẹ ipatẹ ọja agbaye, ẹlẹẹkẹsan iru ẹ, nibi ti awọn ọlọja, oniṣowo yoo ti fi ọja wọn han kaakiri agbaye lati ipinlẹ naa.
 
Ọna ara la gbọ pe ipatẹ ọja yii ti wọn pe ni Trade Fair, gẹgẹ bi awọn alakoso ileeṣẹ  Chamber of Commerce, Industry, Mines and Agriculture n'ipinlẹ naa, iyẹn KWACCIMA ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin laipẹ yii.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ kẹjọ si ogunjọ ninu oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni eto ipatẹ ọja naa yoo waye niluu Ilọrin, nibi ti awọn ọlọja ati oniṣowo kaakiri agbaye yoo ti kopa.

Aarẹ ileeṣẹ naa, Alaaji Ọlalekan Fatai Ayọdimeji, lakoko to n sọrọ sọ pe igbagbọ ati idaniloju ti wa wi pe ipatẹ ọja to fẹẹ waye l'ọdun yii yoo ju eyi to waye l'ọdun 2021 to kọja lọ.
 
Nigba to n sọ ibi ti ipatẹ ọhun yoo ti waye, o ni inu gbagede papa iṣere naa, iyẹn State Stadium Complex to wa niluu Ilọrin ni yoo ti waye, ti awọn akopa yoo si jẹ ki gbogbo agbaye mọ ohun ti iwọn n ṣe.
 
Bakan naa lo ni akori eto ipatẹ ọdun yii l'awọn pe ni "Harmony Through Commerce", to si jẹ ko di mimọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gangan ni yoo ṣiṣọ loju ipatẹ naa lati bẹrẹ ni ibamu p
elu agbekalẹ.

Aarẹ naa tun sọ siwaju pe awọn ti n ṣiṣẹ takuntakun papọ pẹlu awọn ileeṣẹ nal-nla ati kereje-kereje, ti mọ awọn ẹgbe National Association of Small and Medium Enterprises (NASME), ẹka ti ipinlẹ Kwara; Manufacturers' Association of Nigeria (MAN), ti ẹkun Kwara/Kogi fun agbatẹru.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI