Wahala nla de ba ẹgbẹ oṣelu SDP ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 31, 2022

Wahala nla de ba ẹgbẹ oṣelu SDP ni Kwara


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe ko daju wi pe ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP yoo kopa ninu eto idibo to n bọ lọdun 2023 nipinlẹ Kwara.
 
Ohun ti a gbọ ni pe awọn adari ẹgbẹ naa ko fi orukọ awọn to n gbero lati dije ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe kọja lọ si ajọ eleto idibo, iyẹn INEC ni ibamu pẹlu ofin.
 
Ajọ INEC ninu ofin ti wọn gbe jade, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹ gbọdọ fi orukọ awọn to fẹẹ kopa ninu eto idibo abẹle ranṣẹ si wọn ni ọgbọn ọjọ, ṣaaju akoko idibo abẹle naa.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ẹgbẹ oṣelu SDP n'ipinlẹ Kwara ko fi orukọ awọn ondije s'ipo lẹgbẹ naa ranṣẹ si ajọ INEC laaarin asiko naa, eyi ti wọn lo ṣee ṣe ki ajọ eleto idibo ja wọn danu kuro ninu eto idibo to n bọ.

Ẹnikan to sunmọ ẹgbẹ naa, ẹni to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri ti jẹ ko di mimọ pe awọn adari ẹgbẹ naa ti sare lọ siluu Abuja lati lọ ṣalaye idi ti wọn ko ṣe tete fi orukọ ranṣẹ.
 
Ẹni naa tun fi ye wa pe, kii ṣe ipinlẹ Kwara nikan ni ọrọ yii kan, wọn ni awọn alakoso ẹgbẹ naa lapapọ ko tii fi orukọ awọn oludije s'ipo oṣelu lẹgbẹ naa ranṣẹ si ajọ INEC titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyijn yii, eyi to ṣee ṣe ki wọn ma le kopa ninu eto idibo to n bọ lọna.

Koda, a gbọ pe awọn alaṣẹ naa ti n gbiyanju lati yi ọjọ pada lori awọn fọọmu wọn, bo tilẹ jẹ pe a ko le f'idi rẹ mulẹ.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI