AbdulRazaq yan awọn amugbalẹgbẹ tuntun, o tun f'orukọ awọn miran ranṣẹ fun ipo kọmiṣanna - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 9, 2022

AbdulRazaq yan awọn amugbalẹgbẹ tuntun, o tun f'orukọ awọn miran ranṣẹ fun ipo kọmiṣanna


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi orukọ awọn meji kan, Hajia Sa’adatu Modibbo-Kawu ati Abubakar Sadiq Buhari ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, lati gbe wọn yẹwo fun ipo kọmiṣanna.
 
Yatọ si awọn meji wọnyi, Gomina AbdulRazaq tun ti kede awọn miran gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ tuntun ti yoo ba a ṣiṣẹ papọ ninu iṣakoso to n lọ lọwọ yii.
 
Modibbo-Kawu ati Buhari la gbọ pe wọn wa lati ijọba ibilẹ Ilọrin South ati Edu la gbọ pe wọn yoo ṣoju awọn eeyan wọn ninu iṣejọba to n lọ lọwọ yii.
 
Lara awọn amugbalẹgbẹ ti gomina ṣẹṣẹ yan ni; Mohammed Alhassan (Agric, North); Mohammed Qazeem Abdullahi (Agric, Central); Ismail Belle (Transport, North); Adewara Olugbenga (Teacher, South); Kawala Isiaka Olalabi (Teacher, Central); Shola Babatunde Richard Alayoyo (Agric, South); Rashidat Ayobami Olateju (Urban Market, South); ati Umulkhaera Ahmed Alaye (Urban Market, Central).
 
A gbọ pe iṣẹ awọn amugbalẹgbẹ naa bẹrẹ lai si idaduro, ti wọn si ti pẹlu awọn ti yoo gba owo oṣu kọkanla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI