Adebutu at'awọn eeyan rẹ ni ojulowo oludije lẹgbẹ oṣelu PDP - Ile-ẹjọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 28, 2022

Adebutu at'awọn eeyan rẹ ni ojulowo oludije lẹgbẹ oṣelu PDP - Ile-ẹjọ


Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ti da idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun to paṣẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ naa lọ tun eto idibo abẹle wọn ṣe, lati yan awọn to kaju ẹ ti yoo ṣoju ẹgbẹ ninu eto idibo to wa nita.
 
Lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn ni Onidajọ Fọlaṣade Ojo sọ pe igbimọ amuṣẹṣe, National Working Committee nikan lo lẹtọọ lati ṣagbatẹru eto idibo abẹle.
 
Ile ẹjọ naa paṣẹ pe oun ti da Ladi Adebutu ati gbogbo awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP pada lati dije du ipo.
 
Onidajọ O. Oguntoyinbo ṣaaju asiko yii ti paṣẹ pe oun da idibo abẹle to gbe Adebutu ati awọn oludije s'ipo oṣelu labẹ PDP nu, eyi ti Ṣẹgun Seriki pe.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Ojo paṣẹ pe ki ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission, INEC da orukọ awọn oludije naa pada gẹgẹ bo ti tọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI