Awọn kabaa lo n dari eto iṣejọba n’ipinlẹ Ogun, kii ṣe Dapọ Abiọdun - Ọladipọ pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 10, 2022

Awọn kabaa lo n dari eto iṣejọba n’ipinlẹ Ogun, kii ṣe Dapọ Abiọdun - Ọladipọ pariwo sita


Kọmiṣanna tẹlẹri n’ipinlẹ Ogun, Baṣọrun Olumuyiwa Ọladipọ ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe Gomina Dapọ Abiọdun lo n dari eto iṣejọba n’ipinlẹ Ogun, bi ko ṣe pe awọn kabaa (Cabal) ni, o ni wọn kan fi Abiọdun digẹrẹu lasan ni.


Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ, ẹni to ti f’igba kan ri jẹ olori ile igbimọ aṣofin n’ipinlẹ Ogun, to tun jẹ kọmiṣana f’ọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, ko to pada di kọmiṣanna fọrọ eto aṣa ati irin ajo afẹ labẹ iṣakoso Gomina Ibikunle Amosun lo sọrọ naa niluu Abẹokuta lapiẹ yii.

Lakoko to n b’awọn akọroyin sọrọ, o ni ohun to da oun loju daadaa ni pe kii ṣe Dapọ Abiọdun toun mọ lo n dari ọkọ eto iṣejọba n’ipinlẹ Ogun, bi ko ṣe awọn kabaa ti wọn rọgba yii ka.

O l’awọn ni wọn n sọ ohun to gbọdọ ṣe, ibi to yẹ ko lọ fun un, lati le ri ounjẹ ti wọn jẹ, ati pe okoowo adani ni Abiọdun funra rẹ gbajumọ, kii ṣe ọrọ nipa idagbasoke ipinlẹ Ogun.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe;
“A ni iwe akọsilẹ {catalogue} ti a fi n ṣe ayẹwo nnkan, eyi to sọ fun awọn nipa awọn ibi ti ijọba yii ti ṣe aṣiṣe, debi wi pe otitọ ni erongba lati ni ijọba miran. Akọkọ ni pe, ijọba yii ni ko ni igbaradi lati ṣe eto ilu, wọn nii lọkan tẹlẹ lati di gomina. Lati ọjọ akọkọ, gomina yii ko mọ iyatọ to wa laarin jijẹ gomina, ati olori ileeṣẹ kan. Awọn ọrọ rẹ latilẹ lo n sọ nipa bi a ṣe n dari ileeṣẹ, kii ṣe bi a ṣe n dari ilu. Eeyan ko kan gbọdọ maa sọrọ ṣaa.
 
“Mo ranti daadaa lọdun 2019, ti ijọ Ridiimu n palẹmọ eto ọlọdọọdun wọn kan, asiko naa ni a gbọ pe wọn ji awọn pasitọ ijọ naa meloo kan gbe loju ọna Ṣagamu si Benin. Gomina lọ sibẹ, o si sọ fun gbogbo agbaye wi pe lati ibẹ yẹn, wọn yoo ro gbogbo oko ẹgbẹ opopona ni aadọta mita {50metres} sinu igbo, to si ni eyi yoo tete jẹ k’awọn eeyan maa ri awọn to n bọ lati nu igbo bọ si oju ọna. Ohun to dara ni gomina sọ yii, ṣugbọn titi di asiko ti a n sọrọ yii, ileri naa ko tii wa si imuṣẹ, ki lo de to ṣe ileri naa, ki lo de to sọrọ yii jade? Eyi lo si ṣokunfa ohun to n ṣẹlẹ ninu eto aabo ipinlẹ yii.
 
“Lẹyin eyi nigba ti eto ilẹ Yoruba bẹrẹ sii mẹhẹ, awọn gomina ilẹ Yoruba panupọ lati da Amọtẹkun silẹ, bi mo ṣe n sọrọ yii, mi o ri ipa kankan ti Amọtẹkun n ko niu eto aabo nipinlẹ Ogun. Ṣe ni wọn da wọn silẹ lati gbogun ti awọn ajinigbe, ṣugbọn ojoojumọ ni iwa ijinigbe n ṣẹlẹ. Awọn agbegbe kan wa nipinlẹ Ogun lonii, paapaa julọ agbegbe Rounder si Iṣaga Orile, ko si ọjọ kan ti wọn kii ji eeyan gbe.  A ni awọn ileeṣẹ eleto aabo to ti n ṣiṣẹ tẹlẹ nipinlẹ Ogun, bi a ṣe ni VGN, la ni So-Safe Corps, Sifu Difẹnsi, Ọlọpaa, to fi mọ awọn ologun, niṣe lo yẹ ki ijọba yii ti mu wọn papọ lati le jẹ ki eto aabo dagba soke sii.
 
“Mo wa nipo lati bu ẹnu atẹ lu ijọba nitori pe mo ti wa nibẹ daadaa, mo si mọ bo ṣe n lọ. Ẹ lo si awọn ibomiran nipinlẹ yii, ijọba yii ko ni ipa kan ti wọn n ko nibẹ. Lotitọ, ko si ijọba to le ṣe gbogbo rẹ tan, ṣugbọn iwọnba ti wọn ba le ṣe, ki wọn ṣee si ogo Ọlọrun, ati idunnu araalu. Ẹ lọ si Yewa, ki ẹ lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ, awọn to n gbe ibẹ yẹn le sọ pe ko si nnkan ti ijọba yii n ṣe. O yẹ ki ijọba maa tẹsiwaju ni, o si yẹ ki awọn to ba n gba ijọba maa tẹsiwaju iṣẹ t’awọn ijọba to kuro nibẹ ṣe silẹ ni, ṣugbọn ko ri bẹẹ.
 
“Ko si ijọba to mọ ohun to n ṣe, to maa maa ṣe awawi nipa ohun ti ijọba to kuro nibẹ ṣe, bi wọn ba n fẹ ilọsiwaju. Iwe ofin oye jijẹ, iyẹn ‘Chiefs Law’, ko faaye gba ki ọba maa fi ontẹ lu oloṣelu, ṣugbọn o ṣe ni laanu wi pe awọn ọba ti wa di ẹru f’awọn gomina asiko yii, nitori pe awọn ni wọn n san owo oṣu. A ni lati bọwọ fun ori ade, paapaa ipo ọba ati oloye. Ko yẹ ka maa dunkooko mọ wọn, iru eyi ti ijọba yi n ṣe.
 
“Eyi to ṣoju ṣaara, ti awọn eeyan mọ kaakiri i pinlẹ yii ni pe ijọba to wa nita yii, wọn kii gbọ amọran ti yoo ṣe anfaani f’awọn araalu. Bakan naa, mo tun fẹ ki ẹ mọ pe gomina funra rẹ kọ lo n dari eto ilu yii. Awọn kabaa lo n dari ijọba ipinlẹ Ogun.. Ọpọ awọn nnkan lo ti ko ifasẹyin ba ipinlẹ yii, eyi si lo mu k’awọn eeyan maa kun-sinu. Ọpọ awọn to n kun sinu yii ni wọn ko le ṣee sita gbangba, wọn si n sọ labẹlẹ wi pe nigba ti asiko ba to, iyẹn l’oṣu kẹta, ọdun 2023, awọn yoo jade sita lati di ibo lee kuro lori ipo.
 
“Gbogbo awọn to n fẹ iṣipopada ninu ijọba, kii ṣe nipa ipa tabi agidi, bi ko ṣe nipa gbigbẹkẹle eto dibo to ṣoju ṣaara. Fun idi eyi, a maa ṣe iwọn ti a ba le ṣe, lati rii pe ijọba yii wa si opin l’ọdun 2023.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI