Iwadii bẹrẹ lori awọn tọọgi to lọ fi burẹẹdi dana sun ileeṣẹ INEC l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 10, 2022

Iwadii bẹrẹ lori awọn tọọgi to lọ fi burẹẹdi dana sun ileeṣẹ INEC l'Abẹokuta


Bọ tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a kọ iroyin yii tan ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko tii sọ ohunkohun, ṣugbọn sibẹ, ohun ti a gbọ ni pe iwadii awọn eleto aabo ti bẹrẹ lati rọwọ to awọn tọọgi to lọ dana sun ọfiisi ajọ eleto idibo to wa n'ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Abẹokuta loru mọjumọ oni.
 
Nnkan bi aago kan oru oni la gbọ pe awọn tọọgi ti ko din ni mẹjọ yawọ ileeṣẹ INEC to wa ni adugbo Iyana-Mortuary niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ti wọn si dana sun un.

Wọn ni kani awọn oṣiṣẹ eleto aabo ko tete debẹ ni, o ṣee ṣe ki gbogbo ọfiisi naa jona raurau, ti wọn ko si ni ri ohunkohun mu jade kuro nibẹ, nitori ti wọn sọ pe apa kan ọfiisi naa lo jọna patapata.

Dukia olowo iyebiye, to fi mọ awọn iwe to wulo fun eto oṣelu to n bọ yii la gbọ pe awọn tọọgi naa dana sun mọle.

Wọn ni ṣe l'awọn tọọgi naa fo fẹnsi wọnu ọgba ileeṣẹ INEC ko to di pe wọn bẹrẹ sii ki burẹdi bọ inu bẹntiroolu ti wọn gbe dani, ti wọon si n ju ina sii.

A gbọ pe ṣe ni ọlọdẹ inu ọgba naa farapamọ, to si lọ pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo lori foonu fun iranwọ, ki wọn ma ba a paa mọbẹ.

Ọjọgbọn Niyi Ijalaye to jẹ alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni ẹdun ọkan lo jẹ foun pe iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ lasiko ti eto oṣelu wọle de.

O ni iwadii awọn ọlọpaa at'awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku ti bẹrẹ lati mọ awọn to ṣiṣẹ buruku naa.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI