O ma ṣe o! Eeyan mẹrin ṣofo ẹmi sinu ijamba ọkọ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 18, 2022

O ma ṣe o! Eeyan mẹrin ṣofo ẹmi sinu ijamba ọkọ l'Ogun


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn to ṣalabapade ijamba ọkọ to f'ẹmi eeyan mẹrin ṣofo danu l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii, eyi to waye loju ọna Ṣagamu siluu Abẹokuta.
 
Ohun ti a gbọ ni pe iwaju ileepo Adaranijọ to wa lagbegbe Adedẹrọ ni ijamba naa ti waye ni nnkan bi aago meje irọlẹ.
 
Wọn ni awakọ bọọsi Toyota Sienna to lọ ko sabẹ tirela Sino Truck, eyi to n ko simẹnti lọ loju ọna naa.
 
Babatunde Akinbiyi, to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ aabo oju popona nipinlẹ Ogun, TRACE nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ni eefin ti tirela naa n ṣe, lo ṣokunfa bi mọto ọhun ṣe ko sabẹ rẹ.
 
Akinbiyi sọ pe tirela naa ko ni ina lẹyin, eyi to le jẹ k'awọn to n bọ lẹyin rẹ mọ, to mu ki awakọ naa to n ba ere asapajude lọ sare wọ abẹ rẹ, to si ṣe bẹẹ pa eeyan mẹrin ọtọọtọ.
 
Agbẹnusọ ọhun lo jẹ ka mọ pe AAA307GN ni nọmba idanmọ Toyota Sienna naa, to si tun fi ye wa pe ọkan lara awọn to padanu ẹmi wọn yii ko ku loju ẹsẹ, o ni bi wọn ṣe n gbe e de ọsibitu Federal Medical Centre, Abẹokuta lo dakẹ.
 
O l'awọn to ti gbe awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa ni Ijaye, Abẹokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI