Ọmọ ogun ọdun ati ọdun mejidinlogun to n digunjale dero atimọle ni Delta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 8, 2022

Ọmọ ogun ọdun ati ọdun mejidinlogun to n digunjale dero atimọle ni Delta


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ahamọ ọlọpaa l'awọn gendekunrin meji ti ẹ n woju wọn yii, Desmond Ejinyere ati Joshua Emoefe wa, lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ibọn ilewọ agbelẹrọ ni Desmond, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Joshua, toun jẹ ọmọ ogun ọdun fi n digunjale nipinlẹ Delta.
 
Awọn ọlọpaa ẹkun Orerokpe to wa n'ijọba ibilẹ Okpe la gbọ pe wọn rọwọ to wọn, ti wọn si gba ibọn ti wọn fi n jale lọwọ wọn.


Ibi ti wọn ti n digunjale lọwọ la gbọ pe ọwọ ti tẹ wọn, a gbọ pe ṣe ni wọn yọ ibọn si ẹnikan ninu ile to n gbe, ti wọn si gba foonu iPhone XR kan, iPhone 6s kan, Tecno Spark 2 kan, iPhone Max kan, Camon 19, ati kaadi ATM ẹni naa to jẹ ti ile ifowopamọ UBA.
 
Nigba to n f'idi iroyin naa mulẹ, Bright Edafe to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa sọ pe lotitọ ni, ati pe awọn mejeeji ti n gbatẹgun alaafia l'ọgba wọn, ti wọn si ti n jẹwọ awọn iwa ẹṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI