Opopona tuntun ti Osi-Obbo-Aiyegunlẹ tijọba dawọle yoo pari lọdun yii - AbdulRazaq ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 13, 2022

Opopona tuntun ti Osi-Obbo-Aiyegunlẹ tijọba dawọle yoo pari lọdun yii - AbdulRazaq ṣeleri


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi da gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara loju wi pe atuntṣẹ opopona Osi si Obbo to fi de Aiyegunlẹ n'ipinlẹ naa yoo pari lọdun yii, ti yoo si di lilo fun gbogbo araalu.

Opopona naa to jẹ kilomita mọkanle le lẹyọkan, 11.1km la gbọ pe awọn araalu ti n reti lati aadọta ọdun sẹyin, eyi ti wọn l'awọn iṣakoso to ti n ṣe ko ya s'idi ẹ rara fun igbadun awọn araalu.
 
A gbọ pe irin laaarin awọn opopona yii ko ju iṣẹju mẹwaa lọ, ṣugbọn to n gba awọn arinrin ajo ni iṣẹju marundinlaadọta, 45minutes, pẹlu ọpọlọpọ wahala ati irora.

Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ sọ pe didawọle opopona ọhun, ni lati mu ileri oun ṣẹ lakoko ipolongo idibo toun ṣe lọdun 2019, eyi to ni o di dandan lati mu wa si imuṣẹ.

Nibi ayajọ ọjọ Obbo-Aiyegunle to wa nijọba ibilẹ Ekiti lo ti sọrọ naa laipẹ yii, koda, ti wọn tun fun un ni oye Jagunmolu Atayerọ tiluu Obbo-Aiyegunle.
 
Nibẹ lo tun ti ṣeleri wi pe wọn ko nii pẹ ẹ pari ọgba ikẹkọọ tiluu Osi, ti yoo jẹ ẹka ti fasiti ipinlẹ naa, iyẹn (KWASU), ṣaaju iwọle ọdun to n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI