Ipo ọba ko ṣee fi ṣere lori ọrọ eto aabo - ijọba Kwara gbe oṣuba kare fun Ọba Agboọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 4, 2022

Ipo ọba ko ṣee fi ṣere lori ọrọ eto aabo - ijọba Kwara gbe oṣuba kare fun Ọba Agboọla


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ipa pataki lawọn ọba alaye n ko lori ọrọ eto aabo orileede Naijiria, paapaa ipinlẹ naa, to si ni ko si ọba to ṣee fi ṣere lasiko yii.
 
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo sọrọ naa nibi ayẹyẹ ọdun karundinlogoji ti Elesie tiluu Esie n; ijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara, Ọba Yakub Ibrahim Agboọla (Egunjobi II).
 
Nigba to n sọrọ, igbakeji gomina, Kayọde Alabi sọ pe idagbasoke, oriire ati ilọsiwaju to n de ba ilu Esie fi han daju nipa iru ẹni t'awọn araalu yan gẹgẹ bi ọba wọn.

Gomina AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe iṣakoso bọwọ to pọ f'awọn ọba alaye, to si loun gbe wọn si ipo to ga nitori pe ẹni ọwọ ni wọn jẹ lawujọ.

nibẹ lo ti gbe oṣuba kare fun kabiyesi naa lori ifọwọsowọpọ rẹ nipa bi ba awọn araalu sọrọ lori eto aabo, paapaa nipa wiwa ni ikiyesara, eyi to n mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ilu.
 
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ nibẹ pe ilu Esie di ipo nla mu ninu eto irin ajo afẹ orileede Naijiria, to si ni ijọba oun ṣe pupọ ninu gbagede ibudo igbafẹ eyi to ba ti agbaye mu.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI