Ko si oṣiṣẹ otẹẹli Kwara ti wọn da duro - Alakoso ileeṣẹ Harmony - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 14, 2022

Ko si oṣiṣẹ otẹẹli Kwara ti wọn da duro - Alakoso ileeṣẹ Harmony


Awọn alakoso ileeṣẹ Harmony Holdings to n ṣabojuto otẹẹli Kwara ti pariwo sita wi pe ko si oṣiṣẹ otẹẹli naa kankan ti wọn da duro.

Wọn ni ayederu iroyin ti ko ni otitọ kankan ninu ni wọn gbe jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, pẹlu erongba lati bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
 
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ Harmony Holdings Limited gbe jade lọsan ọjọ Iṣẹgun, wọn ni iroyin ori ayelujara kan lo gbe iroyin ẹlẹjẹ naa jade lai ṣe iwadii kikun.

Wọn ni lara awọn ohun ti mọ iroyin naa si ni gbigbe ayederu iroyin ko ni otitọ ninu jade, ati pe lara awọon ipinnu iroyin ayelujara naa ni lati maa ba ijọba Kwara lorukọ jẹ kaakiri.

Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe atunto ṣi n lọ lọwọ lori otẹẹli naa, sibẹ, iyẹn ko tunmọ si wi pe ijọba ti da oṣiṣẹ kankan duro.

Bakan naa ni wọn fi kun un pe ijọba ti da awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa papọ mọ ileeṣẹ to n ri sọrọ okoowo ati imọ ayelujara, iyẹn Ministry of Business, Innovation and Technology papọ, eyi ti wọn fi n wa awọn ti yoo peregede lati ṣiṣẹ nibẹ, lẹyin ti atunto ati atunṣe ba pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI