Nitori aṣeyọri PDP l'Ogun, ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejo awọn ọdọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 4, 2022

Nitori aṣeyọri PDP l'Ogun, ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejo awọn ọdọ


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari patapata bayii fun ilu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun lati gbalejo ojulowo awọn ọdọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee to n bọ lọna yii, iyẹn ọjọ kẹsan, oṣu kejila, ọdun 2022 ti a wa ninu ẹ yii ni awọn ọdọ yoo peju pesẹ siluu Abẹokuta.

A gbọ pe awọn ọdọ naa fẹẹ rin irin iṣẹgun ti a mọ si 'Victory Walk' kaakiri igboro Abẹokuta lati ṣayẹyẹ jijawe olubori ninu idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to waye laipẹ yii.

Laipẹ yii ni ile ẹjọ kotẹmilọrun paṣẹ pe Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ti awọn eeyan mọ si Lado ati awọn alatilẹyin rẹ ni ojulowo oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, kii ṣe awọn alabosi to wa parọ.

Oludije sipo aṣofin agba orileede Naijiria lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun nigba to n gba awọn aṣaaju ọdọ lẹgbẹ PDP lalejo lonii, o ni iwuri nla lo jẹ foun pe awọn ọdọ ronu nnkan ti yoo mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ naa, paapaa lakoko eto oṣelu to wọle de yii.

Ninu ọrọ olori awọn ọdọ lẹgbẹ PDP, Ọnarebu Ọlasunkanmi Oyejide ti awọn eeyan tun n pe ni Suco sọ pe o di dandan lati ṣajọyọ idajọ naa, nitori pe oriire nla lo jẹ fawọn.

Suco, ẹni to lewaju awọn ọdọ lati ijọba ibilẹ mẹfa to wa laaarin gbungbun lọ sọdọ Aderinokun lonio jẹ ko di mimọ pe awọn gbọdọ fi ẹmi imoore han si ile ẹjọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI