O pari! Wọn rọ awọn meji to n pe ara wọn ni oloye ilu Orile Ilawọ ati Baalẹ l'oye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 12, 2022

O pari! Wọn rọ awọn meji to n pe ara wọn ni oloye ilu Orile Ilawọ ati Baalẹ l'oye

Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe a fi ki awọn to n pe ara wọn ni oloye ati Baalẹ niluu Orile Ilawọ tete tun ero ọkan wọn pa, ki wọn si jẹ k'awọn to n pe wọn ni oloye tete mọ pe orukọ atijọ ni.

AWIKONKO gbọ pe awọn meji kan, Ọgbẹni Lawrence Ogunsanya to n pe ara rẹ ni Akọgun ilu Orile Ilawọ ati Ọgbẹni Ọlabanji Ọlaogun, toun naa n pe ara rẹ ni Ogboye ilu Orile Ilawọ ni wọn ti pada juwe ile fun, ti wọn si ni wọn ko gbọdọ pe ara wọn ni oloye mọ niluu Ilawọ.

Wọn ni Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo, Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba lo pa a laṣẹ wi pe awọn meji naa ko gbọdọ pe ara wọn ni oloye mọ niluu Ilawọ, nitori pe ọna ẹburu ni wọn gba yan wọn s'ipo.

Yatọ si awọn meji yii, wọn ni Ọba Tẹjuoṣo tun ti rọ awọn kan to n pe ara wọn ni Baalẹ niluu Orile Ilawọ bii Baalẹ Ariku at'awọn miran loye.

Gẹgẹ bi igbimọ awọn oloye niluu Orile Ilawọ to wa nijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun ti ṣe sọ, wọn ni k'ẹnikẹni ma ṣe ri awọn eeyan yii gẹgẹ bi ipo ti wọn n pe ara wọn, nitori pe wọn kii ṣe ojulowo oloye, bi ko ṣe pe ojulowo ayederu oloye lasan ni wọn jẹ.

Lawrence Ogunsanya ti wọn rọ l'oye

Nibi ipade ti igbimọ awọn oloye niluu Ilawọ ṣe laipẹ yii, eyi t'awọn akọroyin wa nibẹ, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ko si oloye ilu Ilawọ laaarin Ọlaogun ati Lawrence Ogunsanya.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe Lawrence Ogunsanya kii ṣe oloye niluu Ilawọ latilẹ, sibẹ Ọṣilẹ Oke-Ọna, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo ti rọ ọ loye to n pe ara rẹ, nitori pe oloye meji ko le si lori ipo kan ṣoṣo.

Nibi ipade naa ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe "Ọba Tẹjuoṣo paṣẹ pe ki Lawrence Ogunsanya dẹkun lati maa pe ara rẹ ni oloye niluu Orile Ilawọ, nitori pe ọna ẹburu l'awọn to gba owo lọwọ ẹ fi yan an".

Ẹni to n pe ara rẹ ni Baalẹ Ariku

Osi ilu Ilawọ, Oloye Ajani Olufade to lewaju ipade igbimọ awọn oloye ilu Ilawọ laipẹ yii sọ pe Lawrence Ogunsanya ati Ọlabanji Ọlaogun kii ṣe oloye niluu Orile Ilawọ, nitori naa ki ẹnikẹni ma ṣe ri wọn gẹgẹ bi oloye ilu naa.

Bẹẹ lo sọ pe ko tii si ẹnikẹ́ni lori ipo Ariku gẹgẹ bii Baalẹ, nitori pe Ọba Tẹjuoṣo ti pa a laṣẹ pe ẹni to n pe ara rẹ ni Baalẹ Ariku kan n fi ipo naa lu jibiti ni.

O ni gbogbo awọn to n pe ara wọn ni Oloye niluu Ilawọ to wa labẹ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, ti wọn ko ni iwe ẹri Ọba Tẹjuoṣo lọwọ ni wọn n tan ara wọn jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI