O ṣẹlẹ o! Wọn ji eeyan marundinlaadọta (45) gbe lọjọ ọdun Keresi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 27, 2022

O ṣẹlẹ o! Wọn ji eeyan marundinlaadọta (45) gbe lọjọ ọdun Keresi


Ariwo ibanujẹ lo sọ niluu
Angwan Aku to wa nijọba ibilẹ Kajuru, ipinlẹ Kaduna lọjọ ọdun keresimesi to waye l'ọsẹ to kọja yii nigba ti wọn lawọn ajinigbe yawọ agbegbe naa, ti wọn si ji eeyan marundinlaadọta gbe, koda ti wọn tun pa ẹnikan sibẹ.

 
Ohun ti a gbọ ni pe asiko ti awọn eeyan n gbaradi lati lọ si ṣọọṣi fun ti ayajọ ọjọ ibi Jesu la gbọ pe awọn ajinigbe naa yawọ ilu ọhun pẹlu awọn nnkan ija oloro, ti wọn ṣọṣẹ buruku wọn.
 
Gẹgẹ bi ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe ṣalaye, o sọ pe ọkada l'awọn ajinigbe naa gbe wa, o ni wọn le ni ọgọrun kan, iyẹn awọn ajinigbe ọhun.
 
Opopona to wọ ilu ọhun lo sọ pe wọn gbe ọkada wọn si, ko to di pe wọn yawọ ilu pẹlu ibọn ti wọn da bolẹ, ti wọn si bẹrẹ sii dunkooko mọ awọn aarlu lati tẹle wọn lọ.
 
A gbọ pe niṣe lawọn agbebọn naa n lọ inu ile kọọkan lati ko awọn eeyan jade, ti a si gbọ pe eeyan mẹtalelaadọta ni wọn jigbe, ṣugbọn ti awọn meje pada moribọ kuro lọwọ wọn.
 
Wọn ni asiko ti awọn meje naa n salọ, ni wọn yinbọn pa ẹnikan ninu wọn.
 
Lati nnkan bi aago mẹwaa aarọ ọjọ naa ti wọn ti ji awọn eeyan ọhun gbe, wọn ni ko tii sẹni to gburo wọn, yala boya ki awọn ajinigbe naa pe lati beere owo, tabi duna dura pẹlu awọn eeyan wọn.
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Mohammed Jalige sọ pe oun ko tii gbọ ohunkohun nipa nnkan to jọ mọ iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI