Agba oloṣelu PDP tun ti ba APC lọ ni Kwara, o loun ko fẹẹ ba ẹgbẹ radarada wọnu ọdun tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 8, 2023

Agba oloṣelu PDP tun ti ba APC lọ ni Kwara, o loun ko fẹẹ ba ẹgbẹ radarada wọnu ọdun tuntun


Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, o ti fi n daju pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Kwara ko nii rọwọ mu mọ ninu eto dibọ to n bọ lọna yii, pẹlu b'awọn ọmọ ati agba ẹgbẹ ṣe n ya lọ sinu ẹgbẹ miran.
 
Ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ naa lati ẹkun Kwara South, Alaaji Lateef Ibrahim la gbọ pe o ti kede wi pe oun ko ṣẹgbẹ naa, bi ko ṣe pe ẹgbẹ oṣelu APC loun fẹẹ ṣiṣẹ fun bayii.
 
Alaaji Ibrahim, ẹni to ti figba kan ri jẹ olori ẹgbẹ awọn ọdọ lẹkun Kwara South fẹgbẹ PDP ni wọn lo kọwe fẹgbẹ silẹ lalẹ ọjọ to gbẹyin ninu ọdun to kọja.

Wọn lo sọ pe oun ko fẹẹ ba ẹgbẹ ti ko ni afojusun rere wọnu ọdun tuntun, ati pe ẹgbẹ ti ọkan oun tẹle loun fẹẹ ba ṣiṣẹ papọ lọdun 2023 yii.
 
Alaaji Ibrahim sọ pe gbogbo awọn akanṣe iṣẹ to n mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ Kwara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq n ṣe kaakiri ipinlẹ naa, to si lo di dandan k'awọn ṣagbatẹru ẹ, paapaa bo ṣe ni gomina naa ko fi ẹtaanu ṣe awọn nnkan to n ṣe.
 
Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹyin Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba ana lorileede yii, Bukọla Saraki nijọba ibilẹ Ọffa ni wọn pe Alaaji Ibrahim, to si ti ṣiṣẹ lakoko igba ti Saraki ati Abdulfatai Ahmed jẹ gomina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI