Awọn tọọgi dana sun teṣan ọlọpaa lọsan gangan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 8, 2023

Awọn tọọgi dana sun teṣan ọlọpaa lọsan gangan


Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti wọn lawọn tọọgi yawọ teṣan ọlọpaa to wa ni Umuchu, ijọba ibilẹ Aguata, ipinlẹ Anambra lọsan oni, ọjọ Aiku, Sannde.
 
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to padanu ẹmi rẹ nibi ikọlu ọhun, a gbọ pe niṣe lawọn ọlọpa juba ehoro ni kete t'awọn tọọgi naa yawọ teṣan wọn.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, teṣan ọlọpaa naa wa lara awọn teṣan ti awọn tọọgi dana sun nibi iwọde ifẹhonuhan #EndSARS to waye lọdun 2020.
 
Awọn ọmọ ilu naa labẹ agboorun Umuchu Improvement Union la gbọ pe wọn tun teṣan naa kọ, ko to di pe wọn tun pada lọ dana sun un lonii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI