Aye o! Ọlọkada pokunso l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

Aye o! Ọlọkada pokunso l'Abẹokuta


'Iru ki leyi' lọrọ iyalẹnu nla to n jade lẹnu ọpọ awọn ara adugbo Ṣomẹfun lagbegbe Ijeun-Titun to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, nigba ti wọn deedee ri oku ọkunrin kan ti wọn pe ni Azeez Ṣanusi to n mi jolonjolo loke faanu ile.

Azeez, ẹni ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju iṣẹ ọkada gigun lọ, ni wọn sọ pe wọn ba oku rẹ ni nnkan bi aago marun-un irọlẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ko tii sẹni to le fidi rẹ mulẹ nipa nnkan to fa sababi ni Azeez, baba ọlọmọ kan ṣe gbẹmi ara rẹ lojiji, paapaa ni ibẹrẹ ọdun tuntun.

Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti ṣalaye wi pe latigba ti wọn ti gba ọkada ti Azeez n gun, lo ti n ṣe agbawa kaakiri.

A gbọ pe ni nnkan bi ọdun kan sẹyin ni Azeez lọ gba ọkada lọwọ awọn kan, pẹlu ileri lati maa san owo rẹ pada diẹdiẹ.

Wọn ni Azeez n ṣe daadaa, to si n san owo naa, lojiji la gbọ pe nnkan yiwọ fun un, ti ko si da owo ọkada ọhun pada bo ṣe yẹ.

Eyi lo jẹ ki awọn to gbe ọkada naa fun un lati maa fi ṣiṣẹ gba a lọwọ ẹ, to si jẹ ibanujẹ ọkan fun un.

Ẹdun ọkan ni wọn sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ fun un, ti wọn si ni gbogbo igbesẹ to gbe lati gba ọkada naa pada lo ja si pabo, to si n jẹ ibanujẹ ọkan fun un.

Bo tilẹ jẹ pe Azeez n mu ọti ati siga tẹlẹ, wọn ni latigba ti wọn ti gba ọkada lọwọ ẹ lo tun ti tẹra mọ ọti ati siga mimu, ti wọn si ni niṣe lo n mu bii ko tete ku.

A gbọ pe Azeez ko ba ẹnikẹni sọ ohunkohun ko too gbe igbesẹ lati pa ara rẹ, koda wọn l'awọn kan ṣi rii ni nnkan bi wakati kan ko to di pe wọn ba oku rẹ ninu yara to n gbe.

Ẹnikan to ba akọroyin sọrọ, ẹni naa to ni ka fi orukọ boun laṣiri sọ pe Azeez n da gbe ni, bo tilẹ jẹ pe o ti bimọ kan tẹlẹ.

O ni obinrin kankan ko gbe pẹlu Azeez. O ni ṣadede l'awọn ri oku rẹ nibi to so ara rẹ kọ sii nini yara ẹ.

Lara awọn baba onile to wa nitosi ni wọn sare lọ teṣan ọlọpaa Ibara lati fi to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si l'awọn ọlọpaa lo pada gbe oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ninu ọrọ rẹ sọ pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe oun yoo ṣe iwadii, toun yoo si jẹ ká mọ ohun to ṣẹlẹ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI