Ẹ gba Tinubu, ati gbogbo awọn oloṣelu APC gbọ, ki ẹ si dibo fun wọn - Buhari sọ f'awọn ọmọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 9, 2023

Ẹ gba Tinubu, ati gbogbo awọn oloṣelu APC gbọ, ki ẹ si dibo fun wọn - Buhari sọ f'awọn ọmọ Naijiria


Alaṣẹ orileede Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari ti parọwa f'awọn ọmọ orileede Naijiria lati dibo fun oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progessives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Yinubu ninu eto idibo to n bọ lọna yii.
 
Buhari lo sọrọ naa lonii, ọjọ Aje, niluu Adamawa, ipinlẹ Yola, nibi ipolongo idibo aarẹ ati gomina ẹgbẹ naa to waye.
 
O ni ki gbogbo awọn araalu jade lọpọ yanturu lati dibo fun Tinubu ati gbogbo awọn to n dije labẹ asia ẹgbẹ naa, nitori pe ipinnu rere ni wọn ni f'awọn araalu, paapaa orileede yii.
 
“Mo fẹ ki ẹ tẹsiwaju ninu ọkan yii, ki ẹ si duro ṣinṣin ti ẹgbẹ wa, APC. Mo fẹ ki ẹ gbaruku ti gbogbo awọn oludije patapata lẹgbẹ yii lati ipinlẹ titi de apapọ.
 
“Ẹ lẹ gba Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, Jagaban Borgu, oludije lẹgbẹ wa, pẹlu igbakeji rẹ, Sẹnetọ Kashim Shettima gbọ.
 
“Mo fẹ ki ẹ dibo fun wọn rẹpẹtẹ, ki ẹ si ma jẹ ki agbara naa bọ mọ yin lọwọ, ki ẹ si tun da Adamawa pada si ipo itẹsiwaju.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI