Eeyan mẹfa tun ṣofo ẹmi loju ọna marosẹ Eko s'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 15, 2023

Eeyan mẹfa tun ṣofo ẹmi loju ọna marosẹ Eko s'Ibadan

Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn ara agbegbe Oniwọrọ to wa loju ọna marosẹ Eko si Ibadan laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ana nigba ti ijamba mọto f'ẹmi eeyan mẹwaa ṣofo danu.
 
Nnkan bi aago mẹrin aabọ aarọ ni ijamba ọhun waye, nigba ti wọn sọ pe tirela nla kan ati bọọsi akero lo kọlu ara wọn.

Awọn mọkandinlogun la gbọ pe wọn wa ninu bọọsi naa lakoko iṣẹlẹ yii. Ọkunrin mẹtala ati obinrin mẹfa ti gbogbo wọn si jẹ agbalagba.
 
Ninu ọrọ ti ọga agba lẹka eto irinni ati ajọ ẹṣọ oju popona, Ahmed Umar ṣe ṣalaye, o ni tirela naa lo da wahala yii silẹ pẹlu bi wọn ṣe gbe e saarin ọna.

Umar sọ pe ohun to tubọ ṣokunfa ijamba naa ni bo ṣe jẹ pe ori ere asapajude ni awakọ bọọsi Toyota Hiace naa wa, ki ijanu rẹ too sọnu, ni kete to rii pe ijamba fẹẹ waye.
 
O ni loju ẹsẹ l'awọn mẹwaa ti ku, ti awọn si ti ko awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu Ipara, ti awọn si ko awọn to farapa lọ si ọsibitu Victory to wa niluu Ogere, ipinlẹ Ogun.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI