Gbajumọ ọga ọlọpaa ṣubu lulẹ lojiji, lo ba ku patapata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 15, 2023

Gbajumọ ọga ọlọpaa ṣubu lulẹ lojiji, lo ba ku patapata


Kayeefi nla gbaa lọrọ iku ọga ọlọpaa kan nipinlẹ Eko, SP Mọjeed Salami ṣi n jẹ fun awọn eeyan rẹ, paapaa awọn to gbọ, nitori ti wọn sọ pe ojiji lo ba wọn.
 
Salami ni ọga ọlọpaa ẹkun Sẹmẹ n'ipinlẹ Eko. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja, iyẹn ọjọ kẹwaa, oṣu yii la gbọ pe ọkunrin naa dagbere faye.
 
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ wọn ni ọga ọlọpaa naa ti sọ f'awọn oṣiṣẹ rẹ tẹlẹ wi pe ori n fọ oun, to si lọ si ọsibitu lati lọ gba itọju nibẹ.

Wọn ni bo ṣe kuro l'ọsibitu, to pada s'ẹnu iṣẹ rẹ, ori fifọ naa ko tun lọ. Ko pẹ lo sọ f'awọn oṣiṣẹ rẹ wi pe ki wọn ba oun pe DCO, iyẹn  (Divisional Crime Officer) lati wa ri oun ni ọfiisi.

Wọn ni bo ṣe dide, to fẹ maa lọ, lo ṣubu lulẹ.

Igba ti DCO naa wọnu ọfiisi rẹ, lo ba a nilẹ, nibi to ti n pokaka iku, ko to di pe wọn sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Badagry fun itọju.
 
O jẹ iyalẹnu nla nigba ti wọn sọ fun wọn lọsibitu wi pe oku ni wọn gbe f'awọn, kii ṣe alaaye
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin to f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe kayeefi ni iku ọga ọlọpaa naa jẹ f'awọn, nitori pe ọkan lara awọn akikanju ọga ọlọpaa ni Salami jẹ nigba aye ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI