Nitori ibale ọmọ ọdun mẹjọ to ja, wọn ju Ọlamide, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn si ẹwọn gbere l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 18, 2023

Nitori ibale ọmọ ọdun mẹjọ to ja, wọn ju Ọlamide, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn si ẹwọn gbere l'Ekoo


Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ibalopọ ti ko tọna ati iwa ipa, iyẹn Sexual Offences and Domestic Violence, eyi to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Ekoo ti ju gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Ọlamide Ayọdele sẹwọn gbere lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹjọ kan la gbọ pe Ọlamide fipa ba laṣepọ. Ọmọ naa ni wọn lo jẹ ọmọ ẹni to ran an lọwọ.
 
Nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, Onidajọ Abiọla Ṣọladoye, o ṣapejuwe Ọlamide gẹgẹ bii opurọ nla, alaimoore, alailaanu, ọdaran ati oniwa ibajẹ ti ko nilo lati ṣaanu ẹ.

Onidajọ Ṣọladoye sọ pe awọn ẹri toun ri gba nigba nipa ẹsun ti wọn fi kan ọdaran naa kọja ohun ti wọn le dawọ bo tabi gboju fo da, fun idi eyi, o paṣẹ pe ko lọ lo eyi to ku nigbesi aye ẹ lọgba ẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI