Nnkan de! Gbajumọ tọọgi ti wọn n pe ni Kesari f'ipa ba ọlọmọbinrin laṣepọ ninu mọṣalaṣi n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Nnkan de! Gbajumọ tọọgi ti wọn n pe ni Kesari f'ipa ba ọlọmọbinrin laṣepọ ninu mọṣalaṣi n'Ibadan


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ gbajumọ tọọgi kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Idris, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Kesari ṣi n jẹ f'awọn eeyan, lori bi wọn ṣe lo fipa ba ọlọmọge kan laṣepọ ninu mọṣalaṣi to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
 
Inu mọṣalaṣi naa to wa legbegbe Iwo Road la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, eyi to mu k'awọn musulumi dide lati fẹhonu wọn han si iwa ti ọmọkunrin naa hu.
 
Ọmọbinrin ọhun la gbọ pe o wa ninu aṣọ t'awọn obinrin musulumi maa n wọ, eyi ti wọn n pe ni Nikọọbu (Niqob).
Awọn agbaagba ninu ẹsin Islam la gbọ pe wọn lewaju ifẹhonuhan naa lọjọ Aje, Mọnde, ana kaakiri igboro ilu Ibadan, ti wọn si n pe fun idajọ ododo.
 
Ọkan lara awọn to sọrọ, ṣalaye pe ọkan lara awọn ọmọ gbajumọ olori ọga awọn oṣiṣẹ garaaji ni tọọgi ọhun, ti wọn si ni Idris lorukọ ẹ, ati pe Kesari lawọn eeyan tun mọ si.
 
“Ọjọ Sannde ni iṣẹlẹ buruku naa waye niluu Ibadan, nigba ti ọmọ ọkan lara awọn ọga garaaji yọ kẹklẹkẹlẹ wọ inu mọṣalaṣi, to si f'ipa ba ọmọbinrin naa laṣepọ pẹlu aṣọ Nikọọbu to wa lara ẹ.
 
“Eyi lo bi awọn agba musulumi ninu, ti wọn fi dide lati fẹhonu han l'ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.”
 
 
AWIKONKO gbọ pe ọkan lara awọn olori ẹsin ti wọn n pe ni Skeikh Amubiẹya lo lewaju ifẹhonuhan naa.
 
Bẹẹ la gbọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ Idris to jẹ ọmọ ọga garaaji ti wọn n pe ni Al-Majiri, to si ti wa ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii ọran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI