Ẹ woju awọn ọlọdẹ adugbo ti wọn fipa ba obinrin-ọlọmọge laṣepọ fun wakati mẹrin aabọ n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Ẹ woju awọn ọlọdẹ adugbo ti wọn fipa ba obinrin-ọlọmọge laṣepọ fun wakati mẹrin aabọ n'Ibadan


Iwa 'maa mu t'oju mi kuro' lo ko awọn gendekunrin mẹta ti ẹ n wo yii sinu wahala ti ko daju pe wọn le bọ nibẹ, nitori pe ẹbẹ t'awọn eeyan n bẹ ni pe ki idajọ ododo waye lori wọn, ki wọn si foju winna ofin ọdaran.
 
Awọn mẹtẹẹta la gbọ pe wọn gba gẹgẹ bi ọlọdẹ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Alakia to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nibi ti wọn ti f'ipa ba ọmọbinrin ọlọmọge kan laṣepọ karakara.
 
Ẹsun ifipabanilopọ pẹlu ati idigunjale ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi kan wọn, nigba ti wọon n f'oju wọn han f'awọn akọroyin ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan.
 
Nigba too n foju wọn han, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Adewale Ọṣifẹsọ, ṣalaye pe nnkan bi aago mẹsan alẹ ni ọmọbinrin naa lọ wo ọrẹ rẹ kan lagbegbe Alakia ti awọn mẹtẹẹta yii ti n ṣiṣẹ ọlọdẹ alẹ.
 
Wọn ni b'ọmọbinrin naa ṣe wo adugbo ọhun, ọwọ awọn mẹtẹẹta lo ko si, ti wọn si tẹlee lẹyin bi ẹni pe awọn fẹẹ mu de ibi to n lọ, lai mọ pe iṣẹ buruku ni wọn fẹẹ ṣe fun un.
 
Ọṣifẹsọ ni bi wọn ṣe de agbegbe kan, ni wọn ya si ọna miran, nibi ti wọn ti gba foonu rẹ, ti wọ si tun dukooko iku mọ-ọn, bayii ni wọn ṣe gbe e lọ si ibikibi ti ẹnikẹni ko ti nii gbọ ohun wọn.
 
Siwaju sii lo sọ pe lati aago mẹsan alẹ naa, nnkan bi aago kan kọja iṣẹju marundinlọgbọn ni wọn to ṣẹṣẹ fi silẹ lati maa lọ, lẹyin ti awọn mẹtẹẹta ti f'ipa ba a lopọ tan.

Yatọ si eyi, o ni wọn tun f'ipa mu lati fi owo ranṣẹ si wọn lati ori foonu rẹ nile ifowopamọ to n lo.
 
Alukoro ọlọpaa naa sọ pe awọn mẹtẹẹta ti jẹwọ pe otitọ ni nigba tọwọ tẹ wọn, to si ni awọn ti gba foonu ọmọbinrin naa to wa lọwọ wọn, ati ibọn ti wọn fi n ṣiṣẹ buruku kuro lọwọ wọn.
 
Bẹẹ lo sọ pe wọn yoo foju winna ofin lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI