O ga o! Ibi iṣẹ ni Anita nlọ ko to dawati n'Ikorodu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 13, 2023

O ga o! Ibi iṣẹ ni Anita nlọ ko to dawati n'Ikorodu


Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii la gbọ pe wọn ti n wa ọmọbinrin ti ẹ n wo oju ẹ yii, ti wọn ko si tii le sọ pato ibi to wọlẹ si titi di igba ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.

Anita Favour Nwoke ni wọn pe orukọ ọmọbinrin, ọmọ ọdun mejidinlogun naa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Wọn ni aarọ kutu ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii ni Anita dagbere wi pe oun n lọ si ibi iṣẹ oojọ ẹ.

Ilu Ikorodu, ipinlẹ Eko ni wọn sọ pe Anita n gbe, ibẹ naa lo si ti dawati.


Asiko ti wọn lo yẹ ko pada sile, ti wọn ko si rii, eyi lo mu ki wọn wa a lo, ṣugbọn to pada jẹ iyalẹnu fun wọn nigba ti awọn ara ibiṣẹ rẹ sọ pe ko wa lọjọ naa.

Ki ẹnikẹni to ba mọ bi wọn ṣe le rii tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI