Oku ti wọn fẹ lọọ sin poora l'ọsibitu ni Ṣagamu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 30, 2023

Oku ti wọn fẹ lọọ sin poora l'ọsibitu ni Ṣagamu


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lọrọ oku kan ti wọn loo dawati ni mọṣuari ọsibitu fasiti t'awọn olukọni, iyẹn Ọlabisi Ọnabanjọ University Teaching Hospital to wa niluu Ṣagamu ṣi n jẹ kayeefi, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti oku naa wọlẹ sii.
 
Inu oṣu kẹwaa, ọdun 2022 to kọja la gbọ pe wọn ti gbe oku naa lọ si mọṣuari ti a n sọ yii, ti wọn si lawọn mọlẹbi n san owo to yẹ lori itọju oku naa, ṣugbọn asiko ti wọn fẹẹ sin oku yii lo deedee dawati.
 
AWIKONKO gbọ pe ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii lawọn mọlẹbi oku naa to jẹ obinrin fẹẹ sin-in, ki wọn si fi eeru fun eeru, ati erupẹ fun erupẹ.
 
Igba ti wọn de mọṣuari lati gba oku wọn ni wọn lọrọ di womi-n-woẹ, nigba ti wọn ko ri oku ti wọn fẹẹ gbe nibẹ.
 
Gbogbo oku mọkandinlaadọrin ti wọn lo wa ninu mọṣuari naa ni wọn sọ pe ko si eyi to jọ oku ti wọn wa gbe nibẹ, eyi lo jẹ ki wọn figbe ta.
 
A gbọ pe loju ẹsẹ ti aṣiri oku to poora naa ti tu, lawọn to n ṣọ ibẹ ti na papa bora, ti ko si sẹni to le sọ ibi ti wọn wa titi d'asiko yii.
 
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn to sọrọ ṣe ṣalaye, o ni Ijẹbu Ode ni wọn ti gbe oku naa wa si mọṣuari OOUTH l'oṣu kẹwaa, ko to di pe wọn gbe mọto agboku wa lati gbe oku wọn lọ sin.
 
Ẹni naa sọ pe iṣẹlẹ ọhun ya ọga agba pata fun ọsibitu naa lẹnu, ko da, o lawọn ọlọpaa ti debẹ lati wo nnkan to ṣẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ko tii ri ojutu sii.
 
Dọkita agba l'ọsibitu naa, Dọkita Oluwabunmi Fatungaṣe, ninu ọrọ rẹ sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ibi ti oku naa wọlẹ si, ati pe awọn ti bẹrẹ sii wo aworan akaalẹ wọn lati ri aṣiri ọrọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI