Owo tuntun da wahala silẹ niluu, awọn araalu ko ri owo atijọ paarọ si tuntun, bẹẹ lawọn banki tun ko owo pamọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 29, 2023

Owo tuntun da wahala silẹ niluu, awọn araalu ko ri owo atijọ paarọ si tuntun, bẹẹ lawọn banki tun ko owo pamọ


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lawọn ọmọ orileede Naijiria jadejado, paapaa nilẹ Yoruba ṣi n kọminu lori aisi owo tuntun t'ijọba ṣẹṣẹ gbe jade nita, ati pe banki gan-an ko ko owo tuntun silẹ fun lilo.
 
Oni, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 lawọn ọmọ Naijiria tun pariwo sita wi pe awọn ko ri owo tuntun gba, bẹẹ si lawọn ko ri owo atijọ paarọ si owo tuntun, gẹgẹ bi alakalẹ banki agba orileede Naijiria, Central Bank of Nigeria, CBN.

Banki apapọ orileede yii, CBN lo sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 ni gbedeke ọjọ ti awọn ọmọ Naijiria yoo na igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira, ati ẹgbẹrun kan naira ti wọn n na tẹlẹ gbẹyin, ti wọn yoo si pada bẹrẹ sii na owo tuntun ti wọn bu ọwọ lu.

Gomina Godwin Emefiele ti Banki apapọ sọ pe ko si wi pe wọn yoo fi ọjọ kun ọjọ ti wọn yoo na owo naa gbẹyin, gẹgẹ bi awọn kan ṣe fẹ.

Bakan naa ni banki agba tun paṣẹ fun gbogbo banki lati ṣilẹkun silẹ lọjọ Abamẹta, Satide ana, ati oni ọjọ Aiku, Sannde, ki awọn araalu le lo akoko naa lat ṣe paṣipaarọ owo atijọ ọwọ wọn si tuntun, ṣaaju gbedeke ọjọ ti wọn bu ọwọ lu.

A gbọ pe lẹyin aṣẹ yii, awọn banki ko ko owo sẹnu ẹrọ ti wọn fi n gba owo, iyẹn ATM nita banki mọ, bẹẹ si ni wọn ko kowo tuntun silẹ f'awọn eeyan lati na ninu banki.

Wọn ni b'awọn eeyan ba wọ banki lati gba owo wọn, owo atijọ lawọn oṣiṣẹ banki n ko silẹ fun wọn, bi wọn ba si sọrọ, wọn ni iru ẹni bẹẹ ko nii gba owo rẹ niyẹn.

Bakan naa la gbọ pe idaamu ti n ba ọpọ awọn eeyan to ba fẹẹ gba owo lẹnu ATM, wọn ni awọn banki ko kowo sẹnu ATM mọ f'awọn eeyan lati gba.
 
Ọmọwe Iṣhọla Alade to b'AWIKONKO sọrọ laipẹ yii sọ pe awọn ko ri owo gba nidii ATM t'awọn ti lọ gba owo wọn laarọ oni, ati pe ko si banki to ṣilẹkun f'awọn eeyan lati wọ ibẹ gba owo wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
"Lati bi ọsẹ kan la ti n daamu lori owo ti a ko pamọ si banki. Bi a ṣe n daamu ninu banki, bẹẹ naa la n daamu nita banki ti a ba fẹẹ gba owo wa.

"Ko si banki to ṣilẹkun bi mo ṣe n baa yin sọrọ yii lagbegbe Sango, ipinlẹ Ogun. Yatọ si pe banki ko ṣilẹkun, ko si ATM ti owo tun wa ninu ẹ fun wa lati gba owo. Gbogbo awọn baba ati mama agbalagba lo wa nibi, ti a kan jokoo lai ni afojusun wi pe a maa ri owo wa gba.

"A tun beere idi ti wọn ko fi ko owo sinu ATM lọwọ awọn ẹṣọ aabo banki, isọkusọ ni gbogbo wọn n sọ wi pe ko si eyi to kan awọn. Wọn lawọn alakoso banki lo le ṣalaye  nitori pe ẹṣọ aabo lasan lawọn jẹ.

"Ki ijọba Naijiria ran wa lọwọ lori owo wa. Ọpọ bukata lo wa nilẹ ti a fẹẹ fi owo gbọ, ṣugbọn ti wọn ko ko owo oogun ti a ṣiṣẹ fun, fun wa lati gba. Wahala nla leleyi o."
 
Bakan naa, Ọgbẹni Fumbi Ọladele ninu ọrọ tiẹ lati ilu Ibadan sọ pe
"Ẹkọ nla ni eyi jẹ fun gbogbo awa ọmọ Naijiria wi pe ko si igbẹkẹle kankan ninu banki ti a ni. Bawo la ṣe maa ṣiṣẹ fun owo, ti a ko ni le ri owo ọhun gba. Funra banki ni wọn wa ba mi pe ki n wa maa fi owo mi pamọ s'ọdọ wọn, kii ṣe pe mo lọ bẹbẹ ba wọn.
 
"Mo ko owo mi pamọ sọdọ wọn, pẹlu erongba wi pe wọn yoo daabobo owo mi. Ni bayii, mo fẹẹ gba owo naa, ṣugbọn ko saaye lati gba a. Mi o mọ boya dandan ni ka na owo tuntun."
 
Arabinrin Ọpalọla Adetunji lati Oṣogbo to b'AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe wahala t'awọn n koju pọ ju nnkan ti wọn lero lọ. Obinrin naa to loun n ta ohun elo oun sọ pe ko rọrun fun wọn lati gba owo ni banki.
 
"Irẹsi, ẹwa, gaari, elubọ tutu ni mo n ta. Awọn banki lo wa wi pe ki emi naa ba ti igbalode lọ bi aye ṣe n yi, eyi lo jẹ ki n darapọ lati maa kowo pamọ si banki.
 
"Ko si bi a ṣe fẹẹ lọ ra ọja nigba ti a ko ba ri owo gba. Ki ijọba dide iranlọwọ fun wa o."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI