AbdulRazaq ṣi ọja igbalode to kọ f'awọn ọlọja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 16, 2023

AbdulRazaq ṣi ọja igbalode to kọ f'awọn ọlọja


L'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lawọn ọmọ ipinlẹ Kwara tun fi itan tuntun balẹ pẹlu bi Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ṣi ọja igbalode Gbugbu to wa n'ijọba ibilẹ Edo.

Nibẹ ni Ẹmir tiluu Lafiagi, Alaaji Muhammed Kudu Kawu, ti ṣapejuwe akanṣe iṣẹ naa gẹgẹ bi idagbasoke to de lasiko ti awọn eeyan n reti.
 
Ọkan pataki ni ọja tuntun naa jẹ niluu Edu Patigi.

Alaaji Kudu Kawu ninu ọrọ rẹ sọ pe ọja naa yoo jẹ ki eto ọrọ aje agbegbe naa dagbasoke kọja afẹnuroyin, nitori pe ohun ti wọn ti n reti tipẹ ni.

O ni awọn idagbasoke ti Gomina AbdulRazaq ti n ṣe latigba to ti de ori ipo jẹ iwuri, nitori pe ipinlẹ naa to wa ni ipo ẹyin tipẹ, ti wa lara awọn ipinlẹ to n lewaju lasiko yii ni Naijiria.
 No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI