Aṣiri Ramọni, gbajumọ ọmọ lanlọọdu to digun ja tẹnanti lole tu l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 12, 2023

Aṣiri Ramọni, gbajumọ ọmọ lanlọọdu to digun ja tẹnanti lole tu l'Oṣogbo


Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, sibẹ iyalẹnu lo jẹ f'awọn eeyan to gbọ pe ọmọ gbajugbaja lanlọọdu kan niluu Oṣogbo lọ ja tẹnanti baba rẹ lole, to si ko gbogbo ẹru inu ṣọọbu wọn pata, eyi ti ko din ni miliọnu mẹfa aabọ naira.
 
Ṣekoni Ramọni, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni wọn pe ọmọ lanlọọdu ọhun.

Tẹnanti naa ni wọn lo gba ṣọọbu nla kan lọwọ baba Ṣekoni, nibi to ti n ta eroja ara ọkọ ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta (500).
 
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, sọ pe ọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun ti a wa yii lọwọ tẹ Ṣekoni, ati pe awọn ọlọpaa ẹkun Dugbẹ lo rọwọ to o.
 
O ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ ọjọ naa ni tẹnanti to gba ṣọọbu lọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti wi pe boun ṣe ṣilẹkun wọ ṣọọbu laaarọ ọjọ naa, loun ṣakiyesi pe awọn adigunjale ti wa fọ ṣọọbu oun, ti wọn si ti ji pupọ ọja toun n ta ko.
 
Ẹni naa ni owo to le ni miliọnu mẹfa aabọ naira ni iye ọja ti wọn ji ko ninu ṣọọbu oun to wa lagbegbe Ajegunlẹ, eyi lo jẹ ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii.
 

Ko pẹ rara ti Ọpalọla fi sọ pe ọwọ tẹ Ramọni, ti wọn si gba gbogbo ẹru to ji ko naa gbe.
 
O ni laipẹ, lai jinna, Ramọni yoo foju ba ile ẹjọ lati gba idajọ to tọ sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI