Awọn tọọgi yawọ ṣọọṣi Kerubu l'Ondo, wọn danu sun dukia - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 12, 2023

Awọn tọọgi yawọ ṣọọṣi Kerubu l'Ondo, wọn danu sun dukia


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato nipa awọn to yawọ ṣọọṣi kan ti wọn pe ni Motailatu Church of God, ẹka ti Oke-Idahun Parish, ti wa nijọba ibilẹ Akurẹ North, ipinlẹ Ondo, ti wọn si danu sun awọn dukia to wa nibẹ.
 
Irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe awọn tọọgi tẹnikẹni ko tii mọ yawọ inu ṣọọṣi naa to jẹ ẹka ṣọọṣi Kerubu ati Serafu, ti wọn si ṣọṣẹ buruku ọhun.
 
Gẹgẹ bi alakoso ijọ naa, Very Rev’d David Akinadewo-Adekahunsi ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin lọjọ Abamẹta Satide, o ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun wọnu ṣọọṣi naa, toun si ohun to ṣẹlẹ.
 
O ni atupa to wa lori pẹpẹ, eyi ti wọn bajẹ lo pe akiyesi oun si iṣẹlẹ naa, toun si ri bi awọn afọku igo ṣe kun gbogbo ilẹ inu ọgba ṣọọṣi.
 
Siwaju sii lo sọ pe lara awọn dukia ti wọn bajẹ ni apoti ọrẹ ati idamẹwaa, aga ijokoo, pẹlu awọn ohun elo miran bii iwe orin ati bẹẹbẹẹlọ.
 
Alakoso ijọ naa, Akinadewo ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Arẹmọlẹkun, sọ fawọn akọroyin pe oun ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, toun si nigbagbọ pe iwadii kikun yoo fẹsẹ mulẹ laipẹ.
  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI