Ẹ ma ṣe da Aarẹ Buhari lohun, ẹ maa na owo naira atijọ lọ - Dapọ Abiọdun sọ f'awọn ọmọ ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 17, 2023

Ẹ ma ṣe da Aarẹ Buhari lohun, ẹ maa na owo naira atijọ lọ - Dapọ Abiọdun sọ f'awọn ọmọ ipinlẹ Ogun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti sọ fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun lati tẹsiwaju nipa nina awọn owo naira ti awọn eeyan n na tẹlẹ, nitori pe ile ẹjọ agba orileede yii nikan lo ni aṣẹ igbẹyin lọwọ.
 
Abiọdun lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun lakoko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ Kristẹni, Christian Association of Nigeria, ẹka t'ipinlẹ naa ṣepade.
 
O ni ile-ẹjọ ti paṣẹ wi pe ki awọn araalu tẹsiwaju lati maa na owo naa lọ, fun idi eyi, ko si ohun kan to n da awọn araalu duro lati maa na owo naa.
 
“Aṣẹ ti waye lati ile ẹjọ agba orileede, ile ẹjọ to si ga julọ niyẹn nilẹ wa, to si ti paṣẹ pe ki a ṣi maa na owo naira naa lọ. Fun idi eyi, mo bẹ yin pe ki ẹ ma ṣe fa wahala, bi ko ṣe pe ki ẹ tẹsiwaju lati maa na owo naa lọ.
 
“Mo fẹẹ rawọ ẹbẹ lori ipenija ati iṣoro tawọn eeyan n koju lasiko yii lorileede yii. Mo fẹ ki ẹ mọ daju gẹgẹ bii gomina pe, mi o mọ nnkankan nipa ohun to n ṣẹlẹ yii, mi o lọwọ sii, bẹẹ si ni eyikeyi ninu awọn gomina akẹgbẹ mi ko lọwọ sii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI