Ẹ wo oju akẹkọọ girama to dawati l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 2, 2023

Ẹ wo oju akẹkọọ girama to dawati l'Abẹokuta


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin, inu aibalẹ ọkan nla l'awọn obi ọmọdebinrin ti ẹ n wo oju rẹ yii, Ayọade Sẹmeeat Aderayọ wa, lori bo ṣe d'awati lojiji niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
A gbọ ni ṣe ni wọn ran Ayọade niṣẹ lọ ran nnkan nile to wa nitosi ile wọn lagbegbe Maluu-n-kiẹ, Ifẹdayọ, Ọbada-Oko, ṣugbọn ti ko pada sile latigba naa.
 
Nnkan bi aago mẹfa irọlẹ, ọjọ Aje, Mọnde, ọgbọn ọjọ, oṣu kinni, ọdun 2023 ni wọn ran Ayọade niṣẹ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe ipele to kọgun si aṣekagba, iyẹn SSS2J ni Ayọade wa nile ẹkọ girama ti African Church Grammar School.
 
Ẹnikẹni to ba mọ ibi ti ọmọ naa wa, tabi kofiri rẹ, ko pe awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi 08033937624, 07087867482. tabi ki ẹ kan si ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI