Ẹ wo oju baba at'ọmọ to n jale l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 22, 2023

Ẹ wo oju baba at'ọmọ to n jale l'Ogun


Ṣikun bayii lọwọ ẹṣọ aabo t'ipinlẹ Ogun, iyẹn So-Safe Corps tẹ ọkunrin kan, Abioro Weniwon ati ọmọ rẹ, Abioro Zacchaeus ti wọn n jale.
 
Ilu Ihunbọ to wa nijọba ibilẹ Ipokia lọwọ palaba awọn mejeeji ti segi pẹlu ẹru ti wọn ji ko, ti a si gbọ pe wọn ti lọ fa wọn le awọn ọlọpaa ẹkun Idiroko lọwọ.

Wẹniwọn Abioro, ẹni ọdun marundinlọgọrin kan, Abioro Weniwon, ati ọmọ rẹ, Zacchaeus Abioro toun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ni iroyin fi to wa leti pe wọn ji iwe ilẹ meji ọtọọtọ, ferese ile ati ohun elo mọto (C-Causion) kan.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileeṣẹ ẹṣọ aabo ọhun, Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye fun AWIKONKO, o ni ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja lọwọ awọn tẹ awọn mejeeji.


Yusuf tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn kan lo ta ileeṣẹ wọn lolobo, ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii, to si ni ko pẹ rara ti ọwọ fi tẹ awọn mejeeji.

O l'awọn mejeeji jẹwọ pe lotitọ l'awọn jale ẹsun ti wọn fi kan wọn, ati pe awọn ti lu gbogbo ẹru ti wọn ji ko ni gbanjo fun ẹnikan ti wọn pe ni Bapa Madaki, ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Nigba to n pari ọrọ rẹ, o sọ pe ọga awọn Sọji Ganzalo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa awọn mejeeji le awọn ọlọpaa ẹkun Idiroko lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI